CBN Policy: Buhari pàṣẹ fún báńkì àpapọ́ láti dẹ́kun owó ìrànwọ́ fáwọn tó ń gbé oúnjẹ wọ Nàìjíríà

Ọlọja kan ni idi igba rẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ ni aṣẹ naa yoo ran eto ọgbin labẹle lọwọ

Ni ọjọ iṣẹgun ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari kede si eti awọn gomina to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC pe, oun ti paṣẹ fun banki apapọ ilẹ wa, lati yee se akanse pasi paarọ owo Naira ilẹ wa si tilẹ okeere fun awọn to ba fẹ ko ounjẹ wọ orilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bi aarẹ ṣe sọ, igbesẹ yii yoo dena bi kiko ounjẹ wọle lati ilẹ okeere ṣe n ṣakoba fun idagbasoke eto ọgbin labẹle.

Ṣe ẹ si mọ wi pe ko si bi a ba ṣe fa gburu, ti gburu ko ni fa igbo, eyi lo mu ka ṣe ayẹwo awọn ounjẹ ti a n ko wọ orilẹede Naijiria lati oke okun atawọn to ṣeeṣe ko gbowo lori nitori igbesẹ yii.

Eyi ni awọn ohun jijẹ ti a n ko wọ orilẹede Naijiria lati ilẹ okeere gẹgẹ bii ajọ iṣọkan agbaye fun ọdun 2019 ti gbe kalẹ:

Ohun jijẹ Iye to ba de lẹgbẹrun-lẹgbẹrun
1. Wheat ₦575,811
2. Ireke ₦378,624
3. Wara inu agolo ₦264,530
4. Ẹja inu yinyin ₦220,599
5. Irẹsi ₦121,353
6. Ẹja gbigbẹ ₦76,660
7. Ohun ipese ounjẹ ₦72,567
8.Tomato inu agolo ₦36,254
9. Siga ₦28,907
10. Ọti ₦24,206
11. Ohun elo isebẹ ₦23,506
12. Ṣuga ₦22,604
13. Malt ₦19,330
14. Ọti waini ₦18,387
15. Bọta ₦11,835
16. Ẹlẹrindodo eso ₦11,110
17. Ọti ẹlẹrindodo ₦11,087
18. Iyẹfun iwukara (Yeasts) ₦11,065
19. Margarine ₦9,721
20. Ọbẹ ₦9,538
21. Iyọ ₦8,272
22. elo isebẹ Ginger, Thyme & Spices ₦6,287
23. Buttermilk ₦5,950
24. Soybean Meal ₦4,780
25. Adiyẹ ₦1,963
26. ọka baba ₦1,531
27. Miliki ₦1,479
28. Ẹran maluu inu yinyin ₦1,128
29. Ọti bia ₦1,008
30. Burẹdi ati akara oyinbo ₦987
31. Tea ₦924
32. Epo pupa ₦841
33, Sugars ₦695
34. Epo soya ₦663
35. Fermented Beverages ₦629
36. Chicken ₦628
36. Ewebẹ inu yinyin ₦476
37. Ice Cream ₦429
38. Maluu ₦389
39. Prepared Fruit ₦387
40. Oyin ₦344
41. Ẹran ẹlẹdẹ ₦332
42. Iyẹfun flour ₦292
43. Ewebẹ tutu ₦286
44. Ẹyin ẹyẹ ₦226
45. Ewebẹ gbigbẹ ₦145
46. Sọseeji ₦91
47. Ata ₦86
48. Ẹja Shell ₦82
49. Eso ₦76
50. Iyẹfun gbẹrẹfu ₦73
51. Ọsan ₦72
52. Iyẹfun Wheat ₦62
53. Eso gbigbẹ ₦61
54. olu isebẹ ₦58
55. Iyẹfun Cereal ₦43
56. Tomato ₦39
57. Iṣu kukunduku ₦38
58. Ọgẹdẹ ₦23
59. Iru ₦13
60. Carrot ₦11
61. Ẹgẹ ₦3
62. Ẹja aaye ₦3