Iya Rainbow: Ó yẹ́ ká máa yẹ́ àwọn onítíátà sí ní ààyè, kìí ṣe òkú wọn

Idowu Phillips ( Iya Rainbow) Image copyright Iya Rainbow

Yoruba ni baa ku laa dere, eeyan ko sunwọn ni aaye.

Eyi lo mu ki ilumọọka osere tiata nni, Idowu Phillips, ti gbogbo eeyan mọ si Iya Rainbow fi n ke tantan si gbogbo agbaye pe, yoo dara ki wọn maa se ẹyẹ fun awọn osere tiata lasiko ti wọn ba wa laaye, kii se lẹyin ti wọn ba ku tan.

Iya Rainbow gbe imọran naa kalẹ, lasiko ti ileesẹ Gulf Platform n side ayẹyẹ ti wọn fi n sami ọjọ ibi ọdun kẹtadinlọgọrin rẹ ni olu ileesẹ naa to wa nilu Ibadan, eyi ti awọn gbajumọ osere ori itage lọkan o jọkan, awọn akọroyin pẹlu sọrọ-sọrọ peju si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iya Rainbow, ẹni to dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ileesẹ naa n se ẹyẹ fun oun lasiko ti oun si wa loke eepẹ tun fikun pe, ọpọ isẹ ribiribi ni oun n se gẹgẹ bii agba osere laarin awọn ọjẹ wẹwẹ onitiata nidi hihu iwa to tọ lawujọ ati didẹẹkun wiwọ asọ iwọkuwọ.

Nigba to n sọ iru eeyan ti Iya Rainbow jẹ si, Oloye Toyin aya Adegbọla, ti gbogbo eeyan mọ si Aṣẹwo to re Mecca salaye pe, Iya Rainbow jẹ ẹni to ko ni mọra, oludamọran fun awọn ọdọ, ati awokọse rere ni agbo isẹ tiata nitori pe kii fi oju pa ọmọde rẹ.

Saheed Balogun, ta mọ si Walata, ti oun naa ko gbẹyin nibi ayẹyẹ naa, se apejuwe ọlọjọ ibi naa gẹgẹ bii iya rere to wulo pupọ lagbo isẹ tiata, kii wa isubu awọn ọdọ, to si maa n fun awọn ni imọran loore koore nipa bi a se n gbe ile aye se rere.

Ninu ọrọ tiẹ, Razak Ọlayiwọla, ti gbogbo eeyan mọ si Ojopagogo kede pe, Ajẹ pọnbele ati Aṣẹwo haun-haun ni Iya Rainbow.

O salaye pe Iya Rainbow maa n gba awọn ni imọran bii ẹni pe o mọ ohun to fẹ sẹlẹ lọjọ iwaju ni, ẹnikẹni to ba si tapa si imọran iya naa yoo ge ika abamọ jẹ nigbẹyin ni, idi si niyi ti oun se n pe Iya Rainbow ni Ajẹ pọnbele.

Bakan naa, o ni Iya Rainbow maa n pe oun ni ọkọ oun, ti inu oun si maa n dun, amọ nigba to ya lo ye oun pe, gbogbo ọkunrin ni iya naa maa n pe ni ọkọ rẹ, eyi si tumọ si pe iya naa ko tilẹ mọ iye ọkọ to ni, eyi si lo mu ki oun maa pe ni Aṣẹwo haun-haun.

Awọn gbajugbaja osere miran to tun sọrọ nibi eto iside ọjọ ibi Iya Rainbow naa ni Peju Ogunmọla, Sẹgun Ogungbe, Bọsẹ Akinọla ati Biọla Fowosere, ti gbogbo wọn si gba pe, Iya Rainbow korira kii osere tiata maa si ara silẹ lasiko ti wọn ba n sisẹ, to si maa n rọ wọn lati gbe asa Yoruba larugẹ lọjọkọjọ.

Nigba to n salaye awọn eto ti yoo waye nilu Dubai lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹtadinlọgọrin Iya Rainbow, ati idi ti wọn fi gbe eto naa, eyi ti yoo waye laarin ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹwa si ọjọ Kẹta osu Kọkanla ọdun 2019 lọ silu Dubai.

Ọkan lara awọn oludari ileesẹ to n se agbatẹru eto naa, Arabinrin Juliana Afọ́nrewó kede pe, ọpọ ayẹyẹ ọjọ ibi ni wọn ti se fun Iya Rainbow lorilẹede Naijiria, ọna lati mu iyatọ baa, si lo mu kawọn gbe ti ọdun yii lọ si Dubai.

O fikun pe, ileesẹ naa fẹ fi ẹmi imoore rẹ han si Iya Rainbow fun ọpọ ipa takuntakun to ti ko nidi isẹ tiata, lo mu kawọn seto ayẹyẹ ọjọ ibi ọlọjọ meje naa, nibiti awọn gbajumọ olorin bii Pasuma, ati Dare Melody yoo ti kopa, ti awọn yoo si tun se abẹwo si awọn ibi to se koko nilu ọhun.