Revolution Now: Àwọn tó ń ṣèwọ́de ní ọta ìbọn ológun àti ọlọ́pàá kò dẹ́rù ba àwọn

Awọn ọmọ ologun to wa ni Unity Fountain ni Abuja

Agbegbe Unity Fountain nilu Abuja ko rẹrin rara lọsan ọjọru nitori iwọde ti awọn ajafẹtọ ẹni se.

Iwọde yii ni wọn fi n beere fun itusilẹ oludari ẹgbẹ Revolution Now, Omoyele Sowore to wa ni ahamọ awọn agbofinro, ati awọn eeyan miran ti ọlọpaa mu lasiko iwọde wọn to kọja.

Se ni apapọ awọn osisẹ agbofinro, ninu eyi ti a ti ri awọn ọlọpaa ati awọn osisẹ ologun wa, ti wọn si duro wa wa wa si agbegbe naa, pe ti esinsin ba ta firi, awọn yoo wọn ni.

Akọroyin BBC to wa nibi iwọde naa salaye pe, o to ọkọ nla mẹwaa to ko awọn agbofinro naa wa si ibi ti iwọde ọhun ti waye, ko to di pe awọn oluwọde de sibẹ, lati ri daju pe alaafia jọba ni agbegbe naa.

Lasiko ti wọn n fọrọ werọ pẹlu ikọ̀ BBC, awọn oluwọde naa ni ẹru awọn agbofinro ti oju wọn ko rẹrin naa ko ba awọn rara, nitori paa jẹ, baa lẹru, ko si iku ti yoo pa agba, ti wọn ko ni ba poolo ori rẹ nibẹ.

Wọn fi kun pe, awọn ko ni dẹkun lati maa se iwọde naa fun itusilẹ Soworẹ, ti ẹru ọta ibọn awọn ọlọpaa ati sọja naa ko si ba awọn, o si di igba ti wọn ba tu Soworẹ silẹ, ki awọn to sinmi iwọde.

Bẹẹ ba gbagbe, Omoyele Soworẹ ni awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ gbe si ahamọ lasiko to n leri pe ẹgbẹ Revolution Now yoo se iwọde.

Ajọ DSS naa si tun ti gba asẹ ile ẹjọ lati fi Soworẹ si ahamọ fun ọjọ marundinlaadọta, ki wọn lee raye se iwadi to yẹ nipa idunkooko rẹ eyi ti wọn lo tumọ si pe, o fẹ doju ijọba Buhari bolẹ.