Money laundering: EFCC gbé agbẹjọ́rò àti àna Atiku lọ iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn gbígbé owó tùùlù rìn

Awọn oṣiṣẹ EFCC Image copyright Twitter/EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC gbe Ọgbẹni Abdullahi Babalele tawọn kan sọ pe oun ni ọkọ ọkan lara awọn ọmọbinrin Alhaji Atiku Abubakar lọ ileẹjọ l'Ọjọru.

Ẹsun ti wọn fi kan Ọgbẹni Babalele ni pe wọn gbe owo bi ẹgbẹrun lọna ogoje owo dọla($140,000) rin ṣaaju idibo gbogbogbo ọdun 2019.

Bakan naa, ajọ EFCC ṣafihan Ọgbẹni Uyiekpen Osagie-Giwa to wọn ọpọ gbagbọ pe oun ni agbaẹjọro Atiku lori ẹsun pe o gbe owo bi miliọnu meji dọla ṣaaju idibo gbogbogbo.

Awọn mejeeji lawọn o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Atiku dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP eleyi to ti fidi rẹmi ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti jawe olubori.

Adajọ Nicholas Oweibo sun igbẹjọ siwaju si Ọjọbọ, nigba naa ni yoo dajọ lori beeli ti wọn beere fun.

Adajọ Oweibo ni ki wọn dawọn pada si atimọle ajọ EFCC.