Toyin Abraham: Òṣèré Nollywood ti daya Kolawole Ajeyemi.

Toyin Abraham ati Kolawole Ajeyemi Image copyright Instagram/officialbroadwaytv

Ọrọ ifẹ bi adanwo ni, oṣere tiata, Toyin Abraham ti sẹ ayẹyẹ adehun igbeyawo pẹlu oṣere miiran Kolawole Ajeyemi.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Ajeyemi naa lo ni oyun to wa ninu rẹ.

Awọn obi Toyin, Yeyeluwa Odebunmi, Ọgbẹni Segun Odebunmi wa nikalẹ ninbi eto ọhun to waye nile awọn obi Toyin Abraham.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Sinimá Ajé Ọjà tún so Fathia àti Saheed Balogun pọ̀ nínú Sinimá

Ọpọ lo ti n sọ pe ọrọ ifẹ wa laarin awọn mejeeji lẹyin ti wọn ri wọn pọ loriṣiiriṣii ibi ti wọn ti n ṣe inanwo.

Toyin Abraham gan an fun ra rẹ ko tii sọ ohun kan lori adehun igbeyawo naa, ṣugbọn olusakoso rẹ, Samuel Olatunji popularly ti ọpọ mọ si Bigsam lo fọrọ naa lede loju opo Instagram rẹ.

Bigsam pin oriṣiiriṣii fọto eto adehun igbeyawo ọhun laarin Toyin Abraham ati Kolawole Ajeyemi.

Igbeyawo akọkọ ti Toyin Abraham ṣe pẹlu oṣere tiata miiran, Ọgbẹni Adeniyi Johnson fori ṣanpọn.