Wo àgbáríjọpọ̀ àwọn arugbá Ọ̀ṣun Òṣogbo látìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Osun Osogbo: Ọdọọdún ni Àtáója ń gbàlejò gbogbo Arugbá lásìkò ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo

Ọdọọdun laa ri orogbo, ọdọọdun laa ri awusa, ọdọọdun si laa ri ọmọ obi lori atẹ, amọdun ko si jinna, kẹni ma ri eebu sun jẹ.

Bẹẹ lọrọ ri pẹlu ọdun Ọṣun Ọṣogbo fun tọdun 2019, eyi to ti ko bayii, ti yoo si waye lọjọ́ Ẹti.

Ara awọn eto ti wọn fi n sami ọdun Ọṣun Ọṣogbo si ni ipejọpọ awọn arugba ni aafin Ataoja tilu Osogbo eyi to ti waye bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n salaye ayẹyẹ igbalejo naa, agba ọjẹ kan nilu Osogbo salaye pe, ọna lati fi ẹmi imoore han si gbogbo awọn obinrin to ti ru igba Ọṣun sẹyin lo mu ki Kabiyesi gba wọn lalejo.

Nibi ayẹyẹ igbalejo naa to maa n waye lọdọọdun, ni awọn arugba yoo ti maa jo yika igba Ọṣun, eyi to fihan pe isẹ igba ruru ti wọn se ko ja si asan.

A gbọ pe ifa lo maa n fa ọmọge ti yoo ru igba Ọṣun kalẹ laarin awọn ọmọbinrin ti Ataoja to wa lori oye ba bi.

Ọmọge ti ifa ba si mu yii ko gbọdọ tii mọ ọkunrin, yoo si se isẹ naa titi ti yoo fi wọ ile ọkọ ni.

O ya, ẹ jẹ ka wo bi ayẹyẹ ipejọpọ gbogbo awọn Arugba se lọ nilu Oṣogbo lasiko ọdun Ọṣun Ọṣogbo fun tọdun yii.

Ayédèrú Ọ̀ṣun ni wọ́n ń bọ lónìí, kìí ṣe ojúlówó - Bàbá Ọlọ́ṣun tún figbe ta

Wo ọ̀nà tí orin gbígbọ́ fi ń ṣèrànwọ́ f'ọpọlọ ọmọ ìkókó