Obono-Obla: Buhari ti yan Dayọ Apata lati rọ́pò Obono-Obla

Okoi Obono-Obla Image copyright @NGRPresident

Aarẹ Muhammadu Buhari ti yẹ aga mọ alaga igbimọ to n sewadi lati se awari awọn dukia ijọba to ti sọnu, to si n gba wọn pada, Okoi Obono-Obla, to si ni ko lọ rọọkun nile na.

Atẹjade kan ti akọwe ijọba apapọ, Boss Mustapha fisita lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe Agbefọba agba fun ijọba ilẹ wa, Dayọ Apata ni yoo maa dari igbimọ to n gba dukia ijọba to sọnu pada naa, titi di ọjọ miran, ọjọ rere.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akọwe ijọba apapọ ni aarẹ Buhari gbe igbesẹ naa lọna ati fun Obono-Obla ni anfaani lati dahun awọn ẹsun iwa ọdaran to nii se pẹlu iwa ajẹbanu ti ajọ to n tanna wadi iwa ibajẹ ICPC fi kan-an.

Image copyright @NGRPresident

Bakan naa, Obono-Obla yoo tun jẹjọ lori awọn ẹsun to jẹ mọ sise ayederu iwe ẹri ati ẹsun iwa ajẹbanu lọkan o jọkan eyi ti wọn fi kan-an.

Atẹjade naa tun salaye pe, Obono-Obla yoo si maa naju nile naa titi ti ajọ ICPC yoo fi fẹnu ọrọ jona lori iwadi to n se fun-un.