Facebook: Gbogbo ojú òpó ìròyìn èké ní èdé Afirika pátá ló ń lọ

Ami idamọ oju opo Facebook Image copyright Getty Images

Gbogbo ẹyin tẹ n gbe iroyin eke ni ede abinibi lori ikanni Facebook, ẹ sunmọ bi, tori ọrọ yii kan yin.

Awọn alasẹ ileesẹ Facebook nifọwọkọwọ pẹlu igbimọ to n wadi ọfintoto iroyin nilẹ Afirika, Africa Check, ti gunle isẹ sise awari awọn oju opo ikanni eke ni ede abinibi to lu oju opo Facebook pa.

Eto naa, eyi ti wọn sefilọlẹ rẹ lagbegbe Sahara nilẹ Afirika, ni yoo tun fi aan ede adulawọ miran bii Yoruba, Igbo Swahili, Wolof, Afrikaans, Zulu, Setswana ati Sotho sinu iwadi rẹ. Gbogbo awọn iroyin ti kii ba se ojulowo ti eeyan kan ba gbe jade, ni Facebook yoo maa sun si isalẹ patapata loju opo ẹni to kọọ, ti ko si ni lee maa se alabapin iroyin naa bo se yẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Facebook ni oun n reti abọ lati ọdọ awujọ awọn eeyan to n lo oju opo ikanni wọn lori igbesẹ wọn yii, lọna ati se agbeyẹwo awọn iroyin ti kii se ojulowo.

Bẹẹ ba gbagbe, ọpọ ẹnu lo ti n kun oju opo Facebook latẹyinwa pe o nkopa ninu itankalẹ awọn ayederu iroyin ati ọrọ ikorira lawọn oju opo rẹ.

Image copyright Getty Images

Ni ilẹ adulawọ nikan, o le ni aadoje miliọnu eeyan to n lo oju opo ikanni Facebook.