Toyin Abraham: Ìgbéyàwó la kọ́ gbọ́, ọmọ ló tẹ̀le lọ́jọ́bọ

Image copyright fathiawilliams instagram

Ayọ abara bintin, isubu ti subu lu ayọ nile gbajugbaja osere tiata nni, Toyin Abraham pẹlu bi ọba oke tun se fi ọmọkunrin kan ta lọrẹ.

Laipẹ yii ni ileesẹ BBC Yoruba mu iroyin wa fun yin pe, ilumọọkaosere tiata naa ti segbeyawo pẹlu akẹẹgbẹ rẹ kan Kọ̀lawọle Ajeyẹmi, ti wọn si n reti ọmọ nitori Toyin ti di abarameji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A wa dupẹ bayii pe Toyin Abraham ti ruu ree, to si ti sọọ re.

Image copyright fathiawilliams instagram

Nigba to n kede iroyin ayọ naa loju opo ikansira ẹni Instagram rẹ, toyinabrahamnews, osere tiata naa ni "Oluwa dara, Ọmọọba wa ti de", to si fi ijo sii.

Wayi o, gbogbo awọn akẹẹgbẹ rẹ lagbo tiata ni wọn ti n dawọ idunnu pẹlu rẹ, ti wọn si n ki pe o ku ewu ọmọ.

Bi o ba tun se n lọ, a m aa mu iroyin naa wa fun yin.