El-Zakzaky: Ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn aṣemáṣe ni ìjọba àpapọ̀ fi kan Zakzaky ní India

El-zakzaky Image copyright @imnigeria_org

Ni Ọjọru ni okiki kan pe yangi ti n da si gaari eto iwosan ti wọn gbe kalẹ, fun aṣiwaju ijọ ẹsin shiite ni Naijiria, Ibrahim El-Zakzaky to wa lorilẹede India.

Iroyin to kun ori ayelujara sọ pe dipo iwosan ti o lọ fun lorilẹede India, awuyewuye lori eto aabo rẹ nibẹ lo tun gba aye kan ni ilu Delhi bayii.

Ni ọsẹ to kọja ni ileẹjọ kan nipinlẹ Kaduna, gba fun El-Zakzaky lati lọ gba itọju lorilẹede India, ti o si ṣe bẹẹ gẹgẹ ni ọjọ Aje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ko pẹ ti o de ibẹ ti iroyin ti n jade pe, aṣiwaju ẹsin naa ti n fi apa janu, to si ni wọn n fi awọn oṣiṣẹ alaabo dun mahurumahuru mọ oun atawọn dokita oun ni orilẹede India.

Amọṣa ijọba apapọ Naijiria pẹlu ti fesi pe, awọn ko mọ ohunkohun nipa ẹsun yii, ati pe n ṣe ni El-Zakzaky fẹ maa ṣe bi ọba lorilẹede India.

Image copyright @imnigeria_org

Ninu atẹjade kan ti akọwe agba fun ileeṣẹ eto iroyin labẹ ijọba apapọ fi sita, o salaye pe se ni Zakzaky da ọwọ ru ni kete to gunlẹ si India.

"o beere fun aaye lati maa yan fanda fanda kaakiri bo ṣe wu u, to si ni ki wọn si fi oun wọ si ile itura olowo nla kan dipo ile iwosan to yẹ ko wa eleyi ti awọn alaṣẹ orilẹede India tako nitori pe irinajo lati gba itọju lawọn gbọ pe wọn fun un laṣẹ fun, kii ṣe ti irinajo afẹ."

Ohun ti aṣiwaju ẹsin Shiite naa n sọ fun araye bayi ni pe, awọn osiṣẹ alaabo ti ilẹ yii ati orilẹede India ko faye gba a lati ri awọn dokita rẹ.

O ni eyi lo mu ki oun faake kọri pe oun ko lee jẹ ki Dokita ajeji ti abẹrẹ bọ oun lara o.

Awọn ẹsun aṣemaṣe ti ijọba apapọ̀ fi n kan El-Zakzaky ni ilẹ India niyii:

  • O fẹ funrarẹ yan dokita ti yoo tọju rẹ nibẹ eyi ti ijọba apapọ sọ pe 'o lodi si ilana iṣẹ iṣegun oyinbo'
  • O fẹ ki wọn fi oun wọ si ile igbafẹ olowo nla 5-star hotel kan ni India dipo ile iwosan ti o yẹ ko wa fun itọju
  • O fẹ ki wọn da iwe irinna silẹ okeere rẹ pada fun oun eleyi ti awọn oṣiṣẹ alaabo to ba a rinrinajo lati Naijiria lọ si India ni ko lee ṣeeṣe
  • O n fẹ ki wọn ko awọn ẹṣọ alaabo ati ọlọpaa ti o n ṣọ ọ kuro
  • O beere fun anfani ati maa gba alejo bo ba ṣe wu u ni India.

Awọn alaṣẹ orilẹede India ti wa pinnu lati daa pada si Naijiria nitori "wọn ko fẹ ki o lo orilẹede wọn lati fa oju agbaye si ẹgbẹ rẹ'.

Nitori eyi ijọba apapọ wa ni awọn ti tọrọ aforiji lọwọ ijọba orilẹede India fun 'iwa aṣemaṣe'ti El-Zakzaky hu"