Buhari: Ọwọ́ fẹ́rẹ̀ tẹ àwọn agbébọn lókè Ọya

Buhari Image copyright @GarShehu

Irọ ati arumọjẹ ni gbogbo awọn agbebọn ti wọn n paayan tan, ti wọn wa n pariwo Allahu Akbar n pa.

Aarẹ Muhammadu Buhari ni ko tọ si ọmọ ole ko maa pariwo ọlọpaa n bọ.

Aarẹ Buhari sọ ọrọ yii lasiko to ṣe abẹwo si ibudo awọn atipo eeyan ti eeyan bii ẹgbẹrun kan le aadọta, ti ogun agbebọn Boko haram le kuro nile wa, eyi to wa ni ipinlẹ Katsina.

Aarẹ si ti fi da wọn loju pe, oun yoo dẹkun awọn agbebọn to n dun mọhurumọhuru mọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Buhari ni awọn to n fi orukọ ọlọrun boju pa eniyan, kii ṣe ẹlẹsin tootọ.

O ni o ṣeeṣe o ko jẹ pe wọn ko mọ Ọlọrun ni, abi ko jẹ pe ọrọ wọn ati Ọlọrun ko wọ.

Image copyright @AsoRock

"Gbogbo awọn eeyan to jẹ pe iṣẹ ti wọn mọ ni ṣiṣe ko ju ki wọn pa eeyan lọ, ki wọn si maa pariwo "Allahu Akbar", n pa irọ ni nitori Ọlọrun o ṣe ibi.

O ko lee gbe ibọn tabi ado oloro, ida tabi ọbẹ lati pa alaiṣẹ, ki o si maa pariwo "Allahu Akbar". Ohun ti eyi tumọ si ni pe o ṣeeṣe ki o maa mọ Ọlọrun tabi ki o maa ni igbagbọ ninu rẹ."

"Bakan naa lo tun rọ awọn eeyan agbegbe naa lati joye oju lalakana fii n ṣọ ori nitori pe gbogbo igbesẹ ti awọn agbebọn naa n gbe ko ṣẹyin alami ti awọn kan lara araalu n ṣe fun wọn."