NCS: Òǹwòye kan ní kí ìjọba ṣe àtúnṣe ọgbà ẹ̀wọ̀n àti ìtọ́jú ẹlẹ́wọ̀n

Awọn wọda duro siwaju abawọle ọkan lara ọgba ẹwọn nilẹ wa Image copyright @NLCtoday

Onwoye ohun to n lọ lawujọ kan ti sọ wi pe, bi aare Muhammadu Buhari se yi orukọ ileesẹ to n mojuto ọgba ẹwọn lorilẹede yii pada, si ileeṣẹ to n tọ ẹda sọna, jẹ ohun ti o dara pupọ, ati ohun itẹsiwaju.

Ọjọgbọn Dikirulahi Adewale Yagboyaju, tii ṣe olukọ agba ni ẹka imọ eto oselu ni ile ẹkọ giga fasiti Ibadan, lo sọ ọrọ yi ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọru ni aarẹ Buhari kede pe oun ti ṣe ayipada orukọ ileeṣẹ to n mojuto ọgba ẹwọn, Nigeria Prisons Service si Nigeria Correctional Service, eyi ti yoo maa tọ awọn to ba wa ni ahamọ sọna.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Yagboyaju sọ wipe "igbesẹ yi jẹ igbesẹ ti o wa ni ibamu pẹlu bi awọn orilẹede ti o ti goke agba ni agbaye se n se.

Ọgba ẹwọn ko wa lati fiya jẹ ẹnikẹni, sugbọn o tun jẹ ibi ti wọn ti n tun aye awọn eniyan ti o wa ni ahamọ se pelu."

O tẹ siwaju ninu ọrọ rẹ wipe, yiyi orukọ pada nikan ko to, sugbọn o yẹ ki ijọba gbe awọn igbesẹ ti o wa ni ibamu pẹlu yiyi orukọ pada.

Image copyright @NLCtoday

Onwoye awujọ naa ni, ijọba gbọdọ se amojuto awọn ile ti wọn n ko awọn ẹlẹwọn pamọ, ti wọn ko si ni kun akunfaya mọ.

Bakan naa lo ni bi wọn se n gba awọn osisẹ sẹnu isẹ gbọdọ di atungbeyẹwo ati bi wọn se n se iwuri fun awọn ti o jafafa lẹnu isẹ.

Yagboyaju tun tẹsiwaju pe, ijọba tun gbọdọ ri si bi wọn se n bawọn to n se imẹlẹ lẹnu isẹ wi, eyi ti yoo mu ki ayipada orukọ naa ni ipa gidi lori awọn ọgba ẹwọn wa.

Ọjọgbọn naa wa rọ ijọba apapọ lati mojuto awọn kudiẹkudiẹ to wa ni ileesẹ to n samojuto ọgba ẹwọn nilẹ wa, ki ayipada ti ijọba n se lori ileesẹ naa lee yọri si rere.