Child Abuse: Oyinye Mbadike ní ìbátan òun mu ọti yó ni òun ṣe dín dùǹdú ìyà fun

OPETODOLAPO Image copyright InSTAGRAM/@OPETODOLAPO

Obinrin kan, Oyinye Mbadike tawọn ọlọpaa mu nitori pe o na ọmọkunrin kan, tii se ibatan rẹ, to si tun ti mọ inu akolo aja ti ṣalaye idi abajọ t'oun fi ṣe bẹẹ.

Ninu atẹjade kan ti alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkanah fi ṣọwọ si BBC, Mbadike, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun sọ pe oun ṣina iya f'ọmọ ọdun mẹwaa naa, Chibike EziAmaka, nitori o ti mu ọti yoo.

Obinrin naa Chibike mu ọti amupara debi pe, o fi oko fọ gilaasi ọkọ oun nigba ti ọti to mu n pa a.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye fun BBC pe, agbegbe Aguda nipinlẹ Eko ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

Ọga ọlọpaa, Badmos Dolapo kede isẹlẹ naa loju opo Twitter rẹ sọ pe, lati igba ti fọnran iwa ika yii ti lu ayelujara pa, eyi to n ṣafihan bi obinrin kan ṣe na ọmọdekunrin yii, lawọn ti bẹrẹ si ni wa a kiri.

Fidio ọhun to tan kalẹ lori ayelujara ru ibinu awọn araalu soke, nigba ti wọn ri bi obinrin yii ṣe n fi bẹliiti na ọmọ naa, to si tun sọ si ile aja.

Ọpọ eeyan lo ti n pariwo pe kawọn agbofinro fọwọ sinku ofin mu obinrin yii.

Badmos sisọ loju rẹ pe iranwọ tawọn ọmọ Naijiria se fun ileeṣẹ ọlọpaa nigba ti iṣẹ iwadii n lọ lọwọ lo mu ki ọwọ ọlọpaa tete tẹ obinrin naa.

Image copyright @opetodolapo

Awọn ọlọpaa ti fa ọmọ yii, tii se ọmọ orukan naa, le ijọba ipinlẹ Eko lọwọ.

Ọbinrin yii ti wa ni akolo ọlọpaa bayii, nibi ti wọn yoo ti gbee lọ si ileẹjọ laipẹ.