Seyi Makinde ṣe ìbúra fún kọmísánà tuntun mẹ́rìnlá

Seyi Makinde Image copyright Seyi Makinde

Gomina Ipinlẹ Oyo, Ṣeyi Makinde ti bura fawọn kọmiṣọna mẹrinla to ṣẹṣẹ yan l'Ọjọbọ nileeṣẹ ijọba ni Agodi niluu Ibadan.

Baakan naa ni Gomina Makinde tun pin ileeṣẹ ti onikaluku wọn yoo ti ṣiṣẹ fun wọn lẹyin to bura fun wọn tan.

Wọnyi ni awọn kọmiṣọna mẹrinla naa atawọn ileeṣẹ ẹnikọọkan ti wọn yoo di mu gẹgẹ bi Gomina Ipinlẹ Oyo ti kede rẹ.

 • Amofin Adeniyi John Farinto ni kọmiṣọna fun ileeṣẹ Eto Iṣuna ati aato
 • Ọgbẹni Adeniyi Adebisi ni kọmiṣọna fun ileeṣẹ to wa feto okoowo
 • Ọgbẹni Muyiwa Jacob Ojekunle di kọmiṣọna fun eto ọgbin
 • Ọjọgbọn Oyelowo Oyewo lo jẹ Kọmiṣọna fun eto idajọ
 • Amofin Olasunkanmi Olaleye ni kọmiṣọna fun ileeṣẹ idasilẹ
 • Agbẹjọro Seun Asamu ni kọmiṣọna tuntun fun ileeṣẹ ohun amusagbara
 • Ọgbẹni Rahman Abiodun AbdulRaheem ni kọmiṣọna fun ọrọ ilẹ
 • Oloye Bayo Lawal ni Kọmiṣọna fun fawọn akanse isẹ
 • Asofin Funmilayo Orisadeyi lo jẹ kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ
 • Dokita Bashir Bello lo jẹ kọmiṣọna fun eto ilera.
 • Họnarebu Wasiu Olatunbosun ni kọmiṣọna fun eto iroyin.
 • Ọjọgbọn Daud kehinde Sangodoyin ni Gomina Ipinlẹ Oyo kede rẹ gẹgẹ bi kọmiṣọna fun eto ẹkọ.
 • Ọgbẹni Akinola Ojo ni kọmiṣọna tuntun fun eto inanwo nipinlẹ Oyo.
 • Asofin Kehinde Ayoola lo jẹ kọmiṣọna fun ọrọ ayika