Ayédèrú Ọ̀ṣun ni wọ́n ń bọ lónìí, kìí ṣe ojúlówó - Bàbá Ọlọ́ṣun tún figbe ta
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Osun Osogbo: Àtáója ní káwọn èèyàn wá bọ Ọ̀ṣun lónìí, torí kò ṣe é jígbé,

Ni oni ti ayẹyẹ ọdun Ọsun Ọsogbo n waye, baba Ọlọsun tilu Osogbo, Oloye Ọlayiwọla Adigun tun ti fi igbe ta lẹẹkan si fun BBC Yoruba pe, ayederu Ọsun ni wọn n bọ nilu Osogbo loni, kii se ojulowo.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu wa, Baba Ọlọsun ni ere Ọsun ti wọn n bọ loni kere pupọ si eyi ti wọn bọ ni ọdun to kọja, to si dabi agolo bọnfita.

Baba Ọlọsun to ni ere ojulowo ere Ọsun si wa lọdọ oun, wa rọ Ataoja lati pe oun fun ifikunlukun, to ba fẹ ki oun da ojulowo ere Ọsun pada si ojubọ rẹ ni Osogbo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba to n fesi, Kabiyesi naa dahun pe lati igba iwasẹ ti wọn ti n bọ Ọsun, ere naa ko see ji gbe, nitori naa, ohun ti Baba Ọlọsun n sọ kii se ododo ọrọ.

Ataoja wa rọ awọn eeyan lati wa silu Osogbo loni wa bọ Ọsun, ki wọn si kẹyin si ọrọ ti baba Ọlọsun n sọ.

Agbọn n sẹ, oyin n sẹ, taa wa lo ni ojulowo Ọsun wa lọdọ rẹ?