Ibrahim El-Zakzaky: 'Ó ṣeésẹ kí El-Zakzaky máa lọ òkè òkun fún ìtọ́jú mọ́'

Ibrahim El-Zakzaky Image copyright Twitter/SayyidZakzakyOffice
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori ailera Ibrahim El-Zakzaky

O ṣeeṣe ki olori awọn musulumi Shiite, Ibrahim El-zakzaky maa lanfani mọ lati lọ gba itọju loke okun lẹyin to pada si Naijiria latorilẹede India

Ijọba Naijiria fẹsun kan an pe o fẹ wa awọn orilẹede miiran kunra lati gbaruku tii.

Bakan naa nijọba tun koro oju si iwuwa si El-Zakzaky nigba to wa ni orilẹede India.

Eekan lara awọn oṣiṣẹ eleto aabo sọ fun iwe iroyin Punch pe yoo nira fun ijọba lati fun El-Zakzaky ni iru aye bẹẹ nitori ohun tawọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ jabọ fun ijọba lori eto aabo nilẹ India ko tẹ ijọba lọrun.

Ẹ o ranti wi pe ijọba ti kọkọ duro lori ẹsẹ rẹ tẹlẹ pe ki El-Zakzaky gba itọju nile iwosan to wa ni Naijia.

Ṣugbọn awọn ẹsun ti ijọba fi kan an lorilẹede India lara eyi ti wọn ni o ti n gbero lati ri agbẹjọro rẹ, yoo jẹ ki ijọba ṣe agbyẹwo iroyin tawọn ọtẹlẹmuyẹ mu bọ lati India ki ijọba to gbe igbesẹ miiran.

Ijọba Naijiria figbe ta lọjọ Ẹti pe El-Zakzaky n gbero lati lọ ṣe atipo nilẹ okere, bakan naa ni ijọba sọ pe iwuwasi El-Zakzaky lorilẹede India doju ti ijọba orilẹede naa ati ti Naijiria.

Ijọba fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade kan ti akọwe agba nileeṣẹ eto iroyin ati aṣa, Grace Gekpe fi sita pe iyawo El-Zakzaky tako awọn oṣiṣẹ eleto aabo India ati Naijiria.

Atẹjade ọhun tun sọ pe iyawo El-Zakzaky fẹsun kan awọn oṣiṣẹ eleto aabo pe awọn ni wọn pa awọn ọmọ oun.

Ṣugbọn agbẹnusọ fawọn musulumi Shiite, Ibrahim Musa ni irọ ni ijọba n pa, o ni El-Zakzaky ko gbero lati lọ ṣatipo nilẹ okere.

Bakan naa lo sọ pe ko si ẹni to le gba ijọba gbọ lori ọrọ to ba n sọ nipa Ibrahim El-Zakzaky.

Lọjọ Ẹti ni El-Zakzaky pada si orilẹede Naijiria lati India to ti lọ gba itọju pẹlu aya rẹ.