South Africa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìṣesí Nàìjíríà àti South Africa

Wọn idalu ni iṣelu, bẹẹ gẹgẹ lọrọ ti ri pẹlu iyatọ to wa laarin aṣa ilẹ Naijiria ati ti orilẹede South Africa.

Awọn ọmọ Naijiria ti wọn fi orilẹ-ede South Africa ṣe ibuje ṣalaye pe ki ọlọjọ to de lawọn ọmọ ilẹ naa yoo ti maa fowo pamọ fun eto isinku wọn eleyi ti ẹnikan ko gbọdọ da iru laṣa lorilẹede Naijiria.

Wọn ni ibalopọ gan an ko jọwọn loju ati pe ọmọ ọdun mẹrinla le maa fẹnu ko ẹnu pẹlu ọmọ ọdun mẹrinla mii loju titi ti ẹnikan o si le sọ pe ki lẹ n ṣe ni bẹyẹn.

Awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa tun fikun ọrọ pe awọn ọmọ ilẹ naa kii saaba wọ aṣọ ibilẹ wọn nigba ti wọn ba n ṣe igbeyawo.