Toyin Abraham: Ọ̀pọ̀ èèyàn ní èké ni Mercy Aigbe ń ṣe lórí bó ṣe ki Adeniyi Johnson

Adeniyi Johnson ati Mercy Aigbe Image copyright Instagram/realmercyaigbe

Ọpọ eeyan lori ayelujara lo ti bẹnu ẹtẹ lu bi oṣere tiata Mercy Aigbe ṣe ki Adeniyi Johnson to jẹ ọkọ akọkọ Toyin Abraham to ṣẹṣẹ bimọ.

Mercy Aigbe kọ loju opo Instagram rẹ pe Adeniyi wu oun lori, bẹẹ lo tun gbadura fun un pe ''Eleduwa yoo maa tọ lọna, yoo si fi ibukun si iṣẹ ọwọ rẹ lorukọ Jesu.''

Image copyright Instagram/realmercyaigbe

Bakan naa ni Mercy tun sọ ninu ọrọ rẹ pe ki Adeniyi jẹ ki ohun to ti kọ ja lọ di afisẹyin t'eegun fi aṣọ, ko si jẹ ki ifẹ bori.

Ṣugbọn ọpọ ni eke ni Mercy n ṣe lori ikini rẹ to nii ṣe pẹlu ọmọ tuntun jojolo bi Toyin Abraham ṣẹṣẹ bi pẹlu ọkọ rẹ, Kolawole Ajeyemi.

Emerald fi tiẹ ṣe loju opo Twitter rẹ, o ni ko lo ṣeeṣe ki ọrọ ifẹ da Mercy Aigbe ati Adeniyi Johnson pọ.

O ni rara ka maa ri lọrọ naa.

Awọn da Emerald lohun pe ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ, Olukayode Bakre ni tiẹ sọ pe ko si ibi ti ọrọ ifẹ ko ti le ṣẹlẹ.

Image copyright Instagram/toyinabrahamnews

OTSWC ni o le maa si ohun kankan laarin wọn ṣugbọn ko si ohun tawọn osẹre tiata ko le sẹ.

Yẹyẹ ni Duke of Ikorodu fi ọrọ naa ṣe nigba to sọ pe ọkunrin ọun dabi ọmọ ọdun mẹẹdogun loju oun.

Bakan naa ni Emerald fikun ọrọ rẹ pe ọmọkunrin mi ni Mercy maa n pee.

Awọn eeyan mii tiẹ n beere pe ta ni ọkunrin ti wọn n sọrọ nipa rẹ gan an.