Premier League: Tottenham yọ ṣọ́ọ̀kì lẹ́sẹ̀ , ọ̀mì ni wọ́n ta lọ ní pápá ìṣiré Etihad

Man city ati Tottenham Image copyright Getty Images

Ṣe wọn ni ẹṣin ta-ta-ta, o ku, eeyan rin-rin-rin o sọnu, gbogbo agbara emi ni mo to yii ti Manchester city fi gba ife ẹyẹ Premier league ni saa bọọlu to kọja lo sa pẹlu eyi to fi na Westham mọ ile lọsẹ to kọja ṣugbọn pabo lọrọ jasi fun iks naa nigba to gbalejo Tottenham ni gbagede papa iṣire Etihad lọjọ Abamẹta.

Raheem Sterling ti n ti n da bi ẹdun rọ bi owe lati igba ti saa bọọlu tuntun ti bẹrẹ bayii lo kọkọ gba bọọlu sinu awọn, eleyi to sọ iye goolu to ti gba sinu awọn di mẹrin.

Amọṣa, iks Totenham ko fojuure wo Manchester city lẹyin goolu yii, ni kiakia ni awọn naa daa pada. Eric Lamela lo gba wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelogun.

Eyi lo mu ki ikọ Manchester city pariwo ki lo ṣubu lu mi yii? Ni wọn ba ran Sergio Aguero niṣẹ, loun naa ba tun fi ọkan lee fun totenham lo ba di meji fun Manchester city, ẹyọkan fun Tottenham.

Awọn agbabọọlu Tottenham naa ba tun da ẹsẹ ru fun Mancity ni Lucas Moura ba tun da ekeji naa pada.