Wọ́n fi ẹyin adìyẹ lé Ike Ekweremadu, kúrò níbi àṣeyẹ kan ní Germany

Ike Ekweremadu Image copyright Ike Ekweremadu

Ẹyin eeyan wa, aṣe nnkan n ṣẹlẹ niju ara etile o gbọ ni. Boya wọn si gbọ, wọn fi mọra ni awa o mọ o.

Ẹ n bi mi pe ki lo ṣẹlẹ?

Igbakeji aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ, Sẹnetọ Ike Ekweremadu lawọn ọmọ ẹya apa ila oorun gusu orilẹ-ede Naijiria kan din dundu iya fun lọjọ Abamẹta ni ilu Nuremberg lorilẹ-ede Germany.

Gẹgẹ bi iroyin ti agbọ ṣe sọ, nṣe ni wọn fi iwe pe Sẹnetọ Ekweremadu si ibi eto nla kan ti awọn ọmọ ẹya igbo to n gbe ni ilu naa gbe kalẹ.

Gẹgẹ bi ipe ti wọn pe e, oun ni yoo jẹ alejo pataki nibi eto naa.

Amọṣa, ki a maa deena pẹnu, kaka ki wọn bu ẹyẹ fun un gẹgẹ bi alejo pataki, nṣe ni wọn yẹyẹ aṣofin agba naa.

Koda, ẹyin tutu ni wọn ju luu, wọn ko si tilẹ jẹ ko ri aaye wọle debi pe yoo roju raye ṣe alejo pataki ti wọn pee fun.

Awọn amugbalẹgbẹ ati ọrẹ rẹ kan to ba ikọ BBC sọrọ fi idi rẹ mulẹ, amọṣa wọn bu ẹnu atẹ lu iwa naa.