Insecurity: Buhari pàṣẹ fáwọn ológun láti yìnbọn pàwọn ọ̀daràn tó ń dààlú rú

Muhammadu Buhari Image copyright Twitter/Nigerian Presidency
Àkọlé àwòrán Ọrọ eto aabo Naijiria

Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fawọn ologun pe ki wọn yinbọn pa ọdọran kọdaran to ba n ṣagbatẹru rogbodiyan tabi ikọlu kaakiri orilẹede Naijiria.

Aarẹ ni o ba oun lọkan jẹ bi awọn janduku ti n pawọn alaiṣẹ ati bi wọn ti n sọ ọpọ di alaabọ ara ti wọn si n tun n jawọn lole.

Aarẹ Buhari fọrọ yii lede nibi ti o ti n bawọn ọmọ ologun 17th Brigedi atawọn ọmọogun ofurufu 213 Operational Base niluu Katsina lọjọ Abamẹta.

Buhari rọ awọn ologun naa ti wọn pe ọrukọ wọn ni "Operation Hadarin Daji," lati ṣiṣẹ eto aabo ti ijọba gbe fun wọn takuntakun.

Aarẹ ni ijọba ''da ẹgbẹ ọmọogun yii silẹ lati daabo bo apa iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria lọwọ awọn janduku ti wọn da ilu ru kiri, ati pe iṣẹ wọn ni lati daabo bo orilẹede Naijiria lapaapọ.''

Aarẹ sọ pe oun gẹgẹ bi olori ileeṣẹ ologun Naijiria ''gbagbọ pe awọn ọmọogun koju oṣuwọn lati ṣiṣẹ ti ijọba gbe fun wọn,'' bakan naa ni aarẹ paṣẹ fun wọn pe ki ''wọn o wa awọn ọdanran to n da rogbodiyan silẹ lọ sibi kibi ti wọn ba n farapamọ si, ki wọn si mu wọn kuro nilẹ.''

Buhari ni o to gẹ bayii nitori Naijiria pe alaafia gbọdọ jọba lorilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari ṣeleri pe ijọba ṣetan lati pese ohun elo ijagun ti wọn nilo lati ṣiṣẹ to wa lọwọ wọn.

Lọjọ Abamẹta yii naa ni Aarẹ Buhari pada siluu Abuja lẹyin isinmi ọdun Sallah to lọ ṣe niluu rẹ Daura lati ọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ.