Ike Ekweremadu attack: Igbákejì adarí ilé aṣòfìn àgbà tẹ́lẹ̀ dáríjì àwọn IPOB tó nà mí ní Germany

Ike Ekweremadu Image copyright Facebook/Ike Ekweremadu

Ọrọ naa da bi ọrọ ti Jesu Kristi sọ lori igi agbelebu pe ''Baba dariji wọn, nitori pe wọn ko mọ ohun ti wọn n ṣe.

Bẹẹ gẹgẹ ni igbakeji adari ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja tẹlẹ, Sẹnẹtọ Ike Ekweremadu ti fesi si bawọn ẹya Igbo to ni ọmọ ẹgbẹ IPOB ni wọn ṣe fiya jẹẹ lọjọ abamẹta ni ilu Nuremberg lorilẹede Germany.

Image copyright Facebook/Ike Ekweremadu

Ninu ọrọ ti Sẹnẹtọ Ekweremadu fi soju opo Facebook rẹ, o ni oun ko ni gbe iṣẹlẹ naa sọkan nitori oun mọ pe awọn eeyan ko mọ ohun ti wọn n ṣe.

Ẹgbẹ Ndigbo lo fi iwe pe Sẹnetọ Ekweremadu si ibi eto nla kan ti awọn ọmọ ẹya igbo to n gbe ni ilu naa gbe kalẹ. Gẹgẹ bi ipe ti wọn pe e, oun ni yoo jẹ alejo pataki nibi eto naa.

Kaka ki wọn bu ẹyẹ fun un gẹgẹ bi alejo pataki, nṣe ni wọn yẹyẹ aṣofin agba naa. Koda, ẹyin tutu ni wọn ju luu, wọn ko si tilẹ jẹ ko ri aaye wọle debi pe yoo roju raye ṣe alejo pataki ti wọn pee fun.

Ẹwẹ, ọpọ eeyan atawọn eekan ninu awọn oloṣelu lo ti n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, lara wọn ni alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okere, Abike Dabiri-Erewa to bẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa.

O ni awọn to wa nidi ọrọ naa gbọdọ foju wina ofin.

Bakan naa, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayo Fayoṣe ni ẹni ilẹ ti wọn kii tẹni funh lawọn to fiya jẹ Ekweremadu lorilẹede Germany.

Fayoṣe ni ikọlu yii jẹ ikọlu fun gbogbo ẹya Igbo ati orilẹede Naijiria lapapọ nitori Sẹnẹtọ Ekweremadu jẹ ọkan lara awọn to jẹ ki ijọba awarawa fidi mu lẹ.

Fayoṣe iru awọn eeyan ko yẹ ki wọn maa gbe aarin awọn eeyan lawujọ.

Osita Chidoka ni tiẹ beere lọwọ awọn to yẹyẹ Ekweremadu lati tọrọ aforiji lọwọ rẹ nitori ko mọwọ mẹsẹ nigba ikọ ''Operation Python Dance.''

Chidoka ni Sẹnẹtọ Ekweremadu siwaju awọn igbimọ ti wọn lọ ba arẹẹ Muhammadu Buhari pe ko fi olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu silẹ.