Ogun kidnap: Àwọn ajínigbé gbé ọkọ̀ ojú omi ọlọ́pàá lọ lẹ́yìn tí wọ́n dóòlà ẹ̀mí ọmọ Ìmáàmù

Bashi Makama Image copyright Facebok/Bashi Makama

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe o didan awọn gbọdọ gba ọkọ oju omi agbera pa awọn pada lọwọ awọn ajinigbe.

Ileeṣẹ ọlọpaa doola ẹmi ọmọ imaamu atawọn meji mii ti wọn jigbe lọjọ Ileya lagbegbe Ọde Omi nipinlẹ Ogun.

Abdulazeez Sanni to jẹ ọmọ Imaamu ati Adamson Bamidele pẹlu Adam Jelili ti wọn jigbe leti bọda ipinlẹ Ogun ati ipinlẹ Eko ni wọn ti pada sọdọ awọn ẹbi wọn bayii.

Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bashir Makama sọ pe ko si ohun kan to ṣe awọn eeyan naa nigba tawọn ọlọpaa doola ẹmi wọn.

Ọgbẹni Makama o wa ba afurasi kan ninu wọn ti ibọn wa lọwọ rẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣe ọlọpaa Abimbola Oyeyemi ṣalaye pe awọn ẹbi awọn mẹrin naa ko san kọbọ fawọn ajinigbe ọun.

Ọgbẹni Oyeyemi ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo gba ọkọ oju omi tawọn ajinigbe gbe lọ pada.