Benue clashes: Àwọn agbébọn yìnbọn pa èèyàn mẹ́sàn án ni Benue

Awọn eeyan n gbe oku jade Image copyright Getty Images

Aṣe ododo ọrọ pọnbele ni ọrọ awọn agba to ni oku n sunkun oku akaṣọleri n sunkun ara wọn.

Bi ọrọ ṣe ri gẹlẹ ree o ni agbegbe Tongov ni ipinlẹ Benue nigba ti awọn eeyan kan n fẹ lọ sin oku ọkan lara awọn ijoye pataki lagbegbe naa ti orukọ rẹ n jẹ, Tor Gbev Amaafu ni owurọ ọjọ Satide. Tomije-tomije ni ọgọrọ eeyan to tẹle posi oloye naa fi n sin in lọ si itẹ ikẹyin pẹlu orin aro lọlọkan-o-jọkan lẹnu wọn.

Amọṣa, lojiji ni wọn gbọ ti iro ibọn n dun lakọlakọ. Awọn agbebọn kan lo da awọn eeyan to n gbe oku lọ sin naa lọna. Ki a si to wi, ki a to fọ, eeyan mẹrin ti di oku lẹyin ti ọta ibọn ba wọn. Ọpọlọpọ ninu wọn lo tun fi ara gbọgbẹ ọta ibọn.

Ni igba ti yoo fi di ọjọ isinmi tii ṣe ọjọ Aiku, eeyan marun miran ti dero ọrun ọrun o.

Gẹgẹ bii ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Benue ṣe fi to araalu leti, awọn marun to ku yii kagbako iku wọn lasiko ti awọn kan fi lọ gbẹsan ikọlu wọn laarin ileto Amaafu, Sati Agirigiri ati Ikurav Tiev ni ijọba ibilẹ Katsina-Ala.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ benue, Catherine Anene ṣalaye peawọn funra pe o ṣeeṣẹ ki o jẹ wahala to n bẹ silẹ laarin ẹya Ikurav ati Shitile ni ipinlẹ Benue lẹnu ọjọ mẹta yii.

O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹẹ naa.