Àwọn ọ̀dọ́ ẹ̀yà Hausa kan àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 'Awawa boys' da ìgboro Eko rú

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọ̀dọ́ ẹ̀yà Hausa kan àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 'Awawa boys' da ìgboro Eko rú

Wahala nla kan ti bẹ silẹ laarin awọn ọdọ kan lagbegbe Oke Odo ni ipinlẹ Eko.

Ohun ti awọn iroyin kan n sọ ni pe awọ̀n ọdọ ẹya Yoruba ati awọn akẹgbẹ wọn lati ẹya Hausa ni wọn fija pẹẹta lọjọ aiku bi o tilẹ jẹ wi pe ko tii si ẹni ti o lee sọ ohun ti o ṣokunfa rogbodiyan naa.

Image copyright others

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni ọja Oke odo ni ija naa ti waye, bẹẹni ọpọ dukia lo parẹ sinu iṣẹlẹ naa ti ọpọ eeyan si fara pa pẹlu.

Image copyright others

Ileeṣẹ ọlọpaa ni wahala naa waye laaring awọn ọmọ Hausa kan ti wọn maa n ṣa ilẹ kaakiri atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti orukọ wọn n jẹ Awawa boys.

Image copyright others

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Bala Elkana to ba ikọ BBC news sọrọ ṣalaye pe wọn ti da ikọ ọlọpaa kogberegbe kan si agbegbe naa ti wọn si ti pana wahala ọhun.