Yoruba-Hausa clash: Ọlọ́pàá mú èèyàn márùn ún lórí ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrin Hausa àti Yorùbá l'Eko

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọ̀dọ́ ẹ̀yà Hausa kan àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 'Awawa boys' da ìgboro Eko rú

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu eeyan marun un lori wahala nla to bẹ silẹ laarin awọn Hausa ati Yoruba lọja Ile-epo lọjọ Aiku.

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana sọ pe awọn gba lati agọ ọlọpaa Oke Odo, ede-ai-yede bẹ silẹ nigba ti Hausa kan to n ṣa ilẹ idọti ṣeeṣi ti ọkunrin Yoruba kan to rẹru lori to si ṣubu bẹẹ.

Bayii lawọn mejeeji ṣe fija pẹta, bẹẹ lawọn ẹya wọn da si ija naa lo ba di nla ti awọn ọmọ ita kan ṣi da si ija naa.

Awọn janduku kan lo lanfani yii lati ja ole, koda wọn tun di opopona mọrosẹ ilu Eko si Abeokuta pa.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Ede Aiyede laarin ẹni meji di nla ni ileepo

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni ọja Oke odo ni ija naa ti waye, bẹẹni ọpọ dukia lo parẹ sinu iṣẹlẹ naa ti ọpọ eeyan si fara pa pẹlu.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Awon janduku miran lo ọrọ naa fi jale

Ileeṣẹ ọlọpaa ni rogbodiyan naa ko ba di ti ẹlẹyamẹya tawọn ko ba tete kọwọ ọmọ bọ aṣọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Bala Elkana to ba ikọ BBC news sọrọ ṣalaye pe wọn ti da ikọ ọlọpaa kogberegbe kan si agbegbe naa to pana wahala ọhun.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán ọpọ ọja lo ṣofo si iṣẹlẹ yii

Ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mu lẹ pe ko sẹni to ku ninu iṣẹlẹ naa, bakan naa awọn mẹrin ti wọn ṣeṣe ti n gba itọju nile iwosan.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo gbe awọn afurasi marun un tọwọ ọlọpaa tẹ lọ si ileẹjọ.