Fatai Owoseni: O dìgbà tí mo bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kí ń tó sọ ìpinnu mi

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Fatai Owoseni: O dìgbà tí mo bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kí ń tó sọ ìpinnu mi

Láìpé a máa to sọ àlákalè wa fún aṣeyọri eto aabo ipinlẹ oyo - Fatai Owoṣeni

Olubadamọran tuntun ti Gomina Seyi Makinde yan lori eto aabo ipinlẹ Oyo, Fatai Owoṣeni ti ni igbesẹ pọ ti yoo mu idagbasoke ba ipinlẹ Oyo.Fatai Owoseni to je kòmisónnà ajo ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ ní ìpínlè Èkó àti Benue ni Seyi Makinde kede pe ko bẹre iṣẹ loṣu kẹjọ ọdun yii.

Gege bí ikede tí akọ̀wé agba gómìnà náà Ogbeni Taiwo Adisa fi ṣòwò si awon akoroyin, ní ọjọ́ Kínní, oṣù tí a wà yìí to fidiẹ mulẹ.

O ni èyí ṣe pàtàkì láti lè fòpin sí ìkọlu àwọn daran-daran kaakiri ipinlẹ Oyo tó fi mọ ojú popona marose káàkiri ipinle naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOhun ti Seyi Makinde sọ lẹyin ipade awọn ẹgbẹ alatako

Fatai Owoseni ṣàlàyé fun BBC pe ó di ìgbà tí Oun bá dé orí àga nibise kí oun to le gbe igbesẹ kankan lati dẹkùn iṣoro awọn Fulani ati awọn ajinigbe ọhun.

Owoṣeni ni o digba ti ọwọ oun ba tẹ eeku ida aṣẹ gẹgẹ bii oludamọran ki oun to le ṣalaye awọn ipinnu to ni lori eto aabo lasiko yii.

Kọmiṣonna nigba kan ri naa beere fun asiko diẹ sii ki oju fi fara balẹ rimu ki wọn fi le gbe igbesẹ to yẹ lati koju iṣoro kari aye yii.