SSANU, NASU gbé fásitì Ibadan tì pa nítorí ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ márùn ún

Awọn oṣiṣẹ gbe nnkan di opopona ni ọgba fasiti Ibadan

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti kii ṣe olukọ ni awọn ile ẹkọ giga lorilẹ-ede Naijiria labẹ aburada NASU, NAAT ati SSANU ẹka fasiti ilẹ Ibadan bẹrẹ iyansẹlodi.

Awọn SSANU, NASU ati NAT naa ti gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ marun un lati kilọ fun ijọba apapọ lori awọn ẹtọ wọn ti wọn n beere fun.Iyanṣẹlodi naa bẹrẹ lowurọ Ọjọ Aje lẹyin ti awọn aṣoju ẹgbẹ naa sọ agadagodo si ẹnu ọna abawọle fasiti ilu Ibadan.

Wọn ni, ijọba apapọ n lọra lati mu adehun ṣẹ pẹlu awọn ẹgbẹ naa.

Gẹgẹ bi awọn aṣoju ẹgbẹ naa ṣe sọ, lara ohun ti wọn n bere fun ni ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ naa.

Ọrọ to niiṣe pẹlu awọn ile ẹkọ ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ da silẹ, idunadura ati adehun laarin ẹgbẹ naa ati ijọba apapọ ni'bẹrẹ ọdun yii, ati bẹẹbẹẹ lọ ni ẹdun ọkan wọn.

Alaga awọn oṣiṣẹ agba labe aburada SSANU ni ẹka fasiti Ibadan, amofin Wale Akinrẹmi, ṣe alaye fun awọn oniroyin pe eyii ti o jẹ olori ipenija ni ajẹmọnu awọn oṣiṣe ti kii ṣe olukọ.

O ni iṣẹ iwadii fi idi ẹ mulẹ wi pe irẹjẹ wa ninu iye owo ti wọn fun awọn oṣiṣẹ naa tẹlẹri.

Bo tilẹ jẹ wi pe awọn akẹkọọ ninu ọgba naa ko fẹ ki a gba ohun wọn silẹ, alaye wọn ni wi pe ki ijọba apapọ gbe igbesẹ ti o tọ lati rii daju wi pe rogbodiyan naa di ohun igbagbe.Ni bayii, ọjọ marun un pere ni awọn ẹgbẹ fẹ fi kilọ fun ijọba lati mu adehun ṣẹ.

Alaye wọn ni wi pe iyanṣẹlodi alainigbendeke yoo gbinaya bi ijọba ba kọ lati ṣe ohun ti o tọ lẹhin ọjọ marun un.