Ekiti: Fayemi gbẹ́sẹ̀ lé èdè òyìnbó sísọ fáwọn òṣìṣẹ́ nípinlẹ̀ Ekiti

Kayode Fayemi Image copyright Ekiti state government

Oyinbo sisọ ti di eewọọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ Ekiti bayii.

Ẹ maa jẹ ko ya yin lẹnu o, nitori pe gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmilo paṣẹ bẹẹ ni ọjọ aje. Gomina Fayẹmi ni ede oyinbo sibo ko gbọdọ jẹyọ nibi eto gbogbo to ba jẹ ti aṣa tabi ibilẹ.

Fayẹmi ni ohun kan to jẹ ijọba oun logun ni gbigbe aṣa ati iṣe ga ni ipinlẹ naa pẹlu gbigbe ede Yoruba ati ede Ekiti larugẹ. Gomina Fayẹmi to fi iṣẹ yii ran olori awsn oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ Ekiti, Deji Ajayi fi kun un pe oṣu kejila ọdun yii ni ajọdun aṣa ipinlẹ naa yoo waye.

"Lati oni lọ, ijọba ti gbẹsẹ le sisọ ede oyibo lawọn eto to ba jẹ ti aṣa. Gbogbo awọn to ba n kopa ni eto ibilẹ gbọdọ maa sọ ede Ekiti tabi ede Yoruba."