World Sàngó Festival 2019: Ìyàtọ̀ tó wà láàrín arugbá Ọ̀ṣun Òṣogbo arugbá Ṣàǹgó lóde Ọ̀yọ̀

Awọn oloriṣa Sango pẹlu awọn Arugba Sango nibi ajọdun Sango nilu Ọyọ Image copyright Alaafin Oba Adeyemi III

Ko si tabi ṣugbọn pe bi a ba n sọrọ nipa arugba ninu iṣẹṣe ati Aṣa Yoruba, ajọdun Ọṣun Oṣogbo ni ọkan ọpọ maa n lọ. Ṣugbọn, n jẹ ẹ mọ pe, ajọdun Sango ni ilu Ọyọ pẹlu maa n gbe arugba sita.

Ẹyin ni rara? Otitọ ọrọ ti ko ni abawọn irọ ninu.

Òyìnbó sísọ di èèwọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ekiti

Falana àtàwọn míì péjú síbi àpérò #RevolutionNow l'Eko

'El-Zakzaky lè má láńfààní láti lọ gba ìtọ́jú mọ́ lókè òkun'

Fayemi fojú Alufa to fipa bá ọmọde lòpọ̀ síta l'Ekiti

Ariwo "Allahu Akbar" kò tọ́ sawọn Agbébọn àti Boko Haram - Buhari

Ike Ekweremadu, igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tẹ́lẹ́ rí èèmọ̀ he nilùú Germany!

Lasiko ti wọn ba n ṣe ajọdun Ṣango, paapaa lode Ọyọ, awọn oloriṣa Sango n maa yan Arugba pẹlu lati gbe igba iṣẹmbaye ti ipese fun ajọdun naa yoo wa wa si aafin.

Image copyright Alaafin Oba Adeyemi III

Iyatọ to wa laarin arugba Ọṣun ati arugba Ṣango ni pe nigba ti arugba Ọṣun jẹ obinrin, ọmọ ọkunrin ni arugba Ṣango jẹ.

Awọn ọmọdekunrin ni wọn maa n lo fun igba Sango wọn si maa n ju ẹyọkan lọ pẹlu.

Image copyright Alaafin Oba Adeyemi III

Awọn arugba Sango yii ni yoo gbe igba lati Ṣango Koso ls si ọdọ Iya Naso ni aafin Alaafin.

Lasiko ajọdun ti ọdun yii to n lọ lọwọ ni ilu Ọyọ bayii, Ọtunẹfa ati Iya Naso lo gba awọn arugba mejeeji lalejo laafin Iku baba yeye.

Image copyright Alaafin Oba Adeyemi III