Osun: Ìjọba kédeìsinmi fáwọn òṣìṣẹ́ láti ṣe àjọ̀dún àyájọ́ ọdún Ìṣẹ̀ṣe

Awọn oniṣẹṣe Image copyright Alaafin Oba Adeyemi III

Gbogbo wa la mọ pe gbogbo ọdun Kiristẹni ati musulumi lorilẹede yii ni ijọba apapọ maa n kede isinmi lẹnu iṣẹ fun.

Ọpọ ọmọ orilẹede yii, paapaa julọ awọn ti wọn fi si idi iṣẹse ẹya kọọkan ni wọn ti n fi ẹhonu han lori ohun ti o n faa gan an ti ijọba kii fi kede isinmi lẹnu iṣẹ fun awọn oṣiṣẹ lasiko awọn ọdun iṣẹse.

Nibayii, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti gbe igbesẹ akọ lori rẹ.

Ijsba ipinlẹ Ọṣun ti kede ọjọ iṣẹgun tii ṣe ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun 2019 gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Image copyright Alaafin Oba Adeyemi III

Kii ṣe ori iṣejọba gomina Gboyega Oyetọla ni igbesẹ yii ti bẹrẹ bikoṣe lati ori Rauf Arẹgbẹṣọla to ṣiwaju rẹ.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọrs abẹle fi sita, ijọba ipinlẹ Ọṣun rọ awọn ẹlẹsin iṣẹṣe lati ṣe ọdun wọn naa ni pẹlẹ-putu ki wọn si ṣe iwure fun ijọba ki ohun gbogbo lee lọ nirọwọ rọsẹ, ki eku lee ke bi eku, ki ẹyẹ si maa ke bi ẹyẹ.

Related Topics