Ondo: Gómìnà Akeredolu fa ìjọba lé igbákejì rẹ̀ lọ́wọ́

Rotimi Akeredolu Image copyright @RotimiAkeredolu

Ijọba ipinlẹ Ondo ti ni gomina tuntun.

Orukọ gomina tuntun naa ni Agboọla Ajayi. Ṣaaju bibọ si ipo gomina, Ajayi ni igbakeji gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu.

Amọṣa o, ọjọ mọkanla pere ni Agboọla yoo lo ni ipo gomina ipinlẹ naa ti yoo tun fi pada si ipo rẹ gẹgẹ bi igbakeji gomina.

Ẹ jẹ ki n laa ko yee yin daadaa.

Gomina ipinlẹ Ondo gangan ni Rotimi Akeredolu, ṣugbọn Akeredolu n ls fun isinmi ọsẹ meji to ja si ọjọ mẹrinla ni o fi fa iṣejọba le igbakeji rẹ, Agboọla Ajayi lọwọ gẹgẹ bii adele gomina lẹyin to ti kọwe si ile aṣofin ipinlẹ naa gẹgẹ bi iwe ofin orilẹede Naijiria, ti ọdun 1999 ṣe laa kalẹ,pe igbakeji oun ni yoo maa ṣe iṣẹ gomina titi ti oun yoo fi pada de.

Ọjọ kẹrin oṣu kẹsan ni Gomina Rotimi Akeredolu yoo pada si ẹnu iṣẹ.