Makinde fi orúkọ ọmọ ọdún 27 kan ránsẹ́ sílé aṣòfin ní ìpìnlẹ̀ Ọ̀yọ́

Seun Fakorede Image copyright @TopsyAshaolu
Àkọlé àwòrán Seun Fakorede ọdọmọde to fẹ maa gbe igbesẹ agba

Ọdọmọde naa ni ọgbọn ti yoo wulo fun awujọ wa.

Gomina ipinle Ọyọ, Seyi Makinde ti fi orúkọ Seun Fakorede, ẹni ti o je ọmọ ọdun metadinlọgbọn ránsẹ́ si ile igbimọ asofin ipinlẹ naa, fún ipò kọmíṣónà.

Seun Fakorede ti awọn eniyan mọ si "Phakoo" kẹkọọ jade ni ile iwe Fasiti olododo ti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ile Ifẹ, ni Ọdun 2017.

Orukọ rẹ wa lara awọn orukọ mẹta ti gomina Seyin Makinde fi sọwọ si ile igbimọ asofin ipinlẹ Ọyọ.

Adebo Ogundoyin, ẹni ti o jẹ agbẹnusọ ile igbimọ asofin ipinlẹ Ọyọ lo fi ọrọ naa lede loju opo Facebook rẹ ni ọjọ Aje.

Koda, ọpọ ọdọ lo ti n ki ọdọmọde yii ku oriire ti wọn si n gba imọran awokọṣe rere loju opo BBC Yoruba.

Àkọlé àwòrán Inu ọpọ ọdọ lo ti n dun si igbesẹ ipinlẹ Oyo yii

O ni pe: Laise ani-ani, ile igbimọ asofin ipinle Ọyọ ti gba orukọ Fakorede gẹgẹ bi okan laran awọn ti yoo di kọmiṣọna ni Ọ́yọ."

Iru eeyan wo ni Fakorede Oluwaseun Tenidayo?

Seun Fakorede jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ti a bi ni Idere ni ipinlẹ Oyo ni guusu iwọ oorun Naijiria.

O lọ sile iwe tijọba Government College ni Apata ni ilu Ibadan.

O tun kawe ni Oladipo Alayande School of Science ko to lọ ka nipa imọ nipa ẹrọ ni Fasiti OAU Ile Ifẹ.

Seun kawe nipa ṣiṣẹ alamojuto ni Swiss E- Learning Institute ni Switzerland lọdun 2013.

O jẹ aarẹ ajọ CDS ni ilu Eko lọdun 2018 nigba ti o n sinru ilu (NYSC)

Oun naa lo jẹ aṣoju ikọ Platoon ẹ lọdun 2017 nigba ti o wa ni ipagọ fun sinsin ilẹ baba rẹ.

Nibo lo ti ṣiṣẹ sẹyin?

Ṣeun Fakorode ṣiṣẹ pẹlu ajọ to n risi idagbasoke ati ohun ini ni ipinlẹ Eko, iyẹn Lagos State Development and Property Corporation.

Oun ni oludasilẹ ile iṣẹ Home Advantage Africa to jẹ ile iṣẹ to n rani lọwọ ti kii ṣe tijọba.

Bakan naa lo jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ Boddiemax Online Premium Fashion Brand.

Omo Fakorede naa tun ni alaga igbimọ to n mojuto ile iṣẹ Reasone Innovations.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundamisi: Ọbasanjọ ni ko jẹ k'awọn ọdọ de'po