Mo ti ṣetán láti daríi ìfẹ̀họ́nú hàn lòdì sí ìpànìyàn - Olúwó

Oluwo of Iwoland, HIM Oba (Dr.) Abdulrosheed Adewale Akanbi Image copyright INSTAGRAM/OLUWO OF IWOLAND
Àkọlé àwòrán Moti setan lati dari ifehonu han leyin ti ijọba ti kọ lati ri si eto aabo

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, ti sọ pe oun ti ṣetan lati daríi ifẹhonuhan lodi si ipaniyan ati iwa ibajẹ ti o gbode kan lorilẹ-ede Naijiria.

O bu ẹnu ẹtẹ lu iha ti ijọba kọ si ọrọ ipaniyan ṣowo, ati pe pipaniyan fun ṣiṣe oogun owo buru ju iwa ijinigbe lọ.

Oluwo tẹsiwaju pe, eto aabo ara ilu jẹ ojuṣe akọkọ fun ijọba. O si bu ẹnu ẹtẹ lu iwa ifẹmiṣofo ti o ti di tọrọ-kọbọ lorilẹ-ede yi.

Ninu atẹjade kan lati ọwọ akọwe rẹ̀, Alli Ibraheem, Oluwo pe fun ofin ti o lagbara lodi si awọn agbenipa ati awọn oniwa ibajẹ, lona lati daabo bo emi awọn ara ilu.

O ni pe "O ba ni lọkan jẹ pe ijọba apapọ ko kọbi ara si iwa ipanijaye ti o gbode kan lorilẹ-ede wa.

O tẹ siwaju pe: Lọwọlọwọ yi, awọn eniyan buburu wa ni ibi ti wọn ti n pa eniyan nitori owo ati ipo. Awọn kan ro pe fifi emi eniyan se irubọ je aṣa. Sugbọn ko ri bẹẹ.

Image copyright @BolanleCole
Àkọlé àwòrán Oseni laanu wipe ijọba apapọ ko kọbi ara si iwa ipanijaye ti o gbode kan lorilẹ-ede wa

Kosi aṣa ti o faramọ fifi emi eniyan se irubọ.

Oba Akanbi wa ke pe ẹgbe Afẹnifẹre, ẹgbe ọmọ Oodua, Agbẹkọya, ati awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba miran lati fọwọsowọpọ pelu oun lati dide gbogun ti iwa fifi ẹmi eniyan se irubọ lorilẹ-ede Naijiria.