Ọ̀lẹ, aṣẹ́wó àti oníranú ni àwọn oní tíátà -Ìyá Rainbow
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Mama Rainbow: iṣẹ́ tíátà kò ta sánsán mọ́ bíi ti ayé àtijọ́

Laisi Oluranlọwọ, iṣẹ tiata kò ni pẹ parun - Idowu Phillips

Ogbontarigi oṣere lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin, Oloye Idowu Phillips ti gbogbo aye mọ si Iya Rainbow ti ke gbajere pe ki ijọba dide iranlọwọ.

Iya Oṣumare rọ ijọba lati gbe owo to to owo kalẹ si ẹka fiimu ṣiṣe ko ma baa parun.

Idowu Phillips sọrọ lori iyatọ to ti de ba iṣẹ tiata nisinsinyi ati laye atijo lasiko to n ba akọroyin BBC Yoruba fọrọ jomi tooro ọrọ.

O mẹnuba ẹkọ lẹnu iṣẹ ere ṣiṣe to ṣe koko laye igba naa ati ohun ti awọn oṣere n ṣe laye ode oni pe o yatọ si ara wọnẸ wo adúrú ẹnu tí mó n bọ́ - Jaiye Kuti.

Iya Rainbow sọ akoba ti ayelujara n ṣe lasiko yii fawọn oṣere ati awọn alagbata pe ko jẹ ki iṣẹ ọhun fẹ pé mọ.

Ni afikun, iya Osumare sọrọ lori ohun toju awọn oṣere n ri ati oju ọlẹ, aṣẹwo ati oniranu ti wọn fi n wo oṣere lati aye atijọ.