Nigeria new ministers: Obìnrin méje pèrè nínú ìgbìmọ̀ ìṣèjọba kì í ṣe ìlérí tí Buhari ṣe ní 2015

Buhari ati awọn minisita Image copyright @BashirAhmaad

Aarẹ Buhari ti bura fun awọn minisita ti yoo baa ṣiṣẹ bayii lẹyin ti o ti bura fun wọn ti o si ti fun ọkọọkan wọn ni ojuṣe rẹ.

" Ẹ ba awọn akọwe agba ati olri ileeṣẹ gbogbo to wa labẹ yin ṣiṣẹ pọ daadaa. Ẹ ma si ṣe ṣalai wa ni irẹpọ pẹlawọn minisita ẹgbẹ yin." Ni ọrọ iyanju ti aarẹ fun awọn ọmọ igbimọ rẹ tuntun naa.

Ọpọ lo ri igbesẹ yiyan minisita ni oṣu kẹta saa keji iṣejọba rẹ gẹgẹ bii eyi to tun dan mọran ju bi nnkan ṣe ri ni saa akọkọ lọdun 2015.

Ko da bi ẹni pe iyatọ wa ninu iye ipo ti wọn fun awọn obinrin ninu iṣejọba yii. Meje ni awọn obinrin to wa ninu igbimọ naa, ninu eyi ti mẹrin ti wa ni ipo minisita kekere:

Sharon Ikeazor (Anambra) - Minisita abẹle fun ọrọ ayika

Mariam Katagum (Bauchi) - Minisita Abẹle fun ọrọ ileeṣẹ, idokoowo, ati karakata

Gbemisọla Saraki (Kwara) - Minisita abẹle fun igbokegbodo ọkọ

Sadiya farouq (Zamfara) - minisita fun iṣẹlẹ pajawiri.

Pauline Tallen (Plateau) - Minisita fun ọrọ awọn obinrin

Ramatu Tijani (Kogi)- Minisita abẹle fun olu ilu orilẹede Naijiria, FCT

Zainab Shamsuna Ahmed (Kaduna) - Minisita feto iṣuna ati aato ilẹẹwa

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti fi aidunu wọn han lati igba ti oruks awọn minisita tuntun naa ti bs sita nibi ti wọn ti ni aarẹ Buhari kuna ati mu adehun to ṣe fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria ṣẹ.

Ileri ti aarẹ ṣe lọdun 2015 ni pe oun yoo mu iwe ofin aparo kan o ga jukan laarin akọ ati abo (National Gender Policy)

Bakan naa ni ọmọ ṣe ori ni ile aṣofin apapọ nibi ti o jẹ pe awọn obinrin meje pere ni ile aṣofin agba ati mọkanla ni ile aṣoju-ṣofin.

Lati iṣejọba aarẹ oluṣẹgun Obasanjọ ni ọrọ yii ti n wọ bọ lati labẹ eto iṣejọba alagbada tuntun yii.

Ti ọtẹ yii fẹ dabi eyi to fẹẹ buru julọ fun iyansipo awọn obinrin ninu eto iṣejọba lorilẹede Naijiria.