FRSC dá N443,180 padà fún ẹbí ẹni to ní ìjàmbá mọ́tò

Image copyright @FRSC
Àkọlé àwòrán Lara iṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo ni lati pese aabo fun ẹmi ati dukia awọn ero loju popo

Eyi ko jẹ tuntun pé a n da owo pada fun ẹbi awọn to kagbako ijamba ọkọ -FRSC

Ajọ ẹṣọ oju popo ni Naijiria, Federal Road Safety Corps (FRSC) ni ipinlẹ Kebbi ni awọn ti da owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọta o le ni irirnwo naira pada fun ẹbi awọn to ni ijamba ọkọ.

Ogbẹni Abayọmi Asaniyan to jẹ oludari ẹka ajọ FRSC ni ipinlẹ Kebbi ni ariwa Naijiria lo sọ eyi di mimọ fawọn oniroyin nipinlẹ Kebbi.

O ni awọn ri owo yii lọna meji nibi ijamba ọkọ to ṣẹlẹ ni Birnin Kebbi ati ni ijoba ibilẹ Argungun nipinlẹ Kebbi.

Abayọmi ni ikọ ẹṣọ FRSC ri ẹgbẹrun lọna irinwo le ni ọgọjọ naira nibi ijamba ọkọ to ṣẹlẹ ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ ọdun yii ni opopona marosẹ Argungun si Birnin Kebbi.

Nigba ti wọn wọn ri ẹgbẹrun mẹtalelogoji o le ni ogun naira ni ijamba ọkọ to waye ni opopona Cemetry atijọ ni Birnin Kebbi.

Oga agba FRSC yii ni gbogbo owo naa ni ajọ FRSC ti da pada fun awọn ẹbi awọn ẹni naa lẹyin iwadii ti o yẹ.

O gba awọn oṣiṣẹ FRSC kaakiri Naijiria nimọran lati maa fi ootọ inu ṣiṣẹ bii ti awọn ọmọ abẹ oun.

Image copyright @FRSC
Àkọlé àwòrán Suuru ati ikanju ọgbaagba ni loju popo

Abayọmi ni o tọna ki wọn maa ṣe akọsilẹ ohun gbogbo ti wọn ba ri nibi ijamba ọkọ loju popo ki wọn si maa koo fun awọn ẹbi awọn ti ọrọ kan lasiko.

Bakan naa lo kilọ iwa ibajẹ fawọn oṣiṣẹ pe oju gbogbo n wa lara àwọn oṣiṣẹ ti ọwọ wọn ko ba mọ to.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJoe Igbokwe kò yẹ́ fún ipò ti wọ́n fún nípìnlẹ̀ Eko - Babatunde Gbadamosi

Ni ipari ọgbẹni Abayọmi parọwa fawọn arinrinajo ati awakọ lati ṣe pẹlẹ loju opopona nitori pe ẹmi ko laarọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọ̀dọ́ Naijiria ti sọ̀rọ̀ síta lórí ohun ti wọ́n ń retí lọ́dọ̀ minista tuntun