Kìnìún pa okùnrin ọmọ aadọrin ọdún kan lorilẹ-èdè South Africa

kinihun Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Kinihun oloola iju kuro lẹran aa sin ninu ile

Ọkunrin naa ti gbogbo eeyan mọ si "The Lion Man" ni Pretoria fẹ tun ile kiniun rẹ ṣe lo ba gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Ọmọ aadọrin ọdun kan lo ti gbẹmi mi, nigba ti ọkan lara awọn kiniun ti o n ṣe itọju fun se ikọlu sii ni orilẹ-ede South Africa.

Okunrin naa, Leon van Biljon, ni o wọ ile awọn kiniun naa lọ, ni igba ti o fẹ tun odi ti o yi ile naa ka se, ki kiniun naa to kọluu lati ẹyin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kiniun kii se ara awọn ẹranko ti o yẹ ki awọn eniyan maa sin ninu ile.

Ikọlu yi lo waye ni Mahala View Lodge, ti o jẹ ile oloogbe naa, ni ila-oorun Pretoria.

Gẹgẹ bi iroyin ti o tẹwa lọwọ, bi Leon ṣe n tu odi naa se, ti o si kọ ẹyin si awọn kiniun ti oun se itoju fun, ni ọkan lara wón bu u jẹ ni ọrun.

Lẹyin ti eyi sẹlẹ ni awọn oṣiṣẹ ti o wa ni ayika yin ibọn lu mẹta ninu awọn kiniun naa, ti wọn si ku.

Awọn oṣiṣẹ yi pinnu lati yin ibọn fun awon ẹranko naa lọna lati gbe oku rẹ kuro ni ibẹ.

Image copyright Getty Images

Agbẹnusọ fun awọn ọlọpaa, Connie Moganedi, si ti fi idi ọrọ naa mulẹ.

O sọ pe, Leon figbe ta nigba ti ọkan lara awọn kiniun rẹ kọlu u, ki awón eniyan ayika ibẹ to fi ibọn pa meta ninu awọn kiniun naa, sugbon, ẹpa ko gboro mọ.

Iku oloogbe yi ti mu ki awọn o n woye ohun to n sẹlẹ lawujọ wi pe, kiniun kii se ọkan lara ẹranko ti o yẹ ki awọn eniyan maa sin ninu ile.