Seun Fakorede di kọmísánà ní ìpínlẹ̀ Oyo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

#NotTooYoungToRun: Seun Fakorede ẹni ọdún 27 di kọmísánà l'Oyo

Ọdọmọde ọmọ ọdun mẹtadinlogbọn gba kọmiṣọna nipinlẹ Oyo.

Awọn eeyan kan ti kọkọ ṣe ifẹhonuhan nileeṣẹ Ijọba niluu Ibadan l'Ọjọbọ pe awọn ko faramọ pe ki Seun Fakorode ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa di kọmiṣọna.

Ṣeyi Makinde to je gomina ipinlẹ Oyo, labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP. lo fi forukọ rẹ ranṣẹ sile aṣofin.

Awọn to ṣe iwọde naa ni idi abajọ ni wi pe Fakorede jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako APC.

Lẹyin eyi ni awọn ọdọ miran fariga pe dandan Fakorede gbọdọ di kọmiṣọna nipinlẹ Oyo nitori pe ọdọ ni wọn n fẹ.

Sẹ ilẹkẹ ma ja sile, ma ja sita ni ọrọ ọhun, Lẹyin ọ rẹyin, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo buwọlu iyansipo rẹ l'Ọjọbọ.

Eyi si sọ Fakorede di ọkan lara awọn kọmiṣọna nipinlẹ Oyo.

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti gboriyin fun Seyi Makinde pe awọn ọdọ Naijiria ko kere ju lati di ipo oṣelu mu lasiko yii.