Fraud Allegations: Àjọ FBI mú ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn jìbìtì l'Amẹrika

FBI Image copyright Twitter/FBI

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orilẹede Amẹrika, FBI sọ pe awọn ti mu ọpọ ọmọ Naijiria ninu iwadii awọn to n lọ lọwọ lori ẹsun jibiti.

Olori eto idajọ nilẹ Amẹrika, Nick Hanna lo fidi ọrọ mu lẹ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ l'Ọjọbọ.

Hanna ṣalaye pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria ọun gbimọ pọ pẹlu awọn aṣoju ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ lati lu awọn kan ni jibiti.

O ṣalaye pe ọgọrin lawọn afurasi ọun ti ọpọ wọn si jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.

Hanna fikun ọrọ rẹ pe agbalagbga ti ọjọ ti lọ lori wọn lawọn eeyan yii lu ni jibiti.

Oriṣiiriṣii ẹsun to le ni ẹẹdẹgbẹta ni ajọ FBI fi kan awọn eeyan yii to to bi ọgọrin.

Ẹsun jijale owo wa lara awọn ẹsun ti wọn fi kan ọpọ Naijiria to wa lara awọn afurasi naa.