Fraud Allegations: Abike Dabiri-Erewa rọ àwọn tọ́rọ̀ kàn láti yọjú sí FBI

Internet fraud Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn gbajuẹ ma n lo ẹro ayara bi aṣa lati lu awọn eniyan ni jibiti

Ijọba apapọ ti fi ọrọ lede pe iwa awọn ọmọ Naijiria ti ajọ FBI ṣatẹjade orukọ wọn gẹgẹ bi afurasi oni gbajuẹ, jẹ eyi ti o ti doju ti orilẹ-ede wa.

Bashir Ahmad, ẹni ti o jẹ oludamọran fun aare Muhammadu Buhari lori ọrọ ẹrọ ayelujara, lo fi ọrọ naa lede lori opo Twitter rẹ.

Bakan naa ni awujọ awọn ọmọ Naijiria to n gbe loke okun tun sọ si ọrọ naa pe: "Ti wọn ba fi ẹsun kan eniyan, ko tumọ si pe o ti jẹbi.

A gbagbọ pe ajọ FBI yoo ṣe iwadi fini fini lori ọrọ naa, ti gbogb wa si maa mọ okodoro ibẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olupẹjọ nilẹ Amẹrika, Nick Hanna, sọ pe, ọwọ ṣikun ijọba ti tẹ awọn mẹrinla

O wa rọ awọn ti ọrọ naa kan ti o wa lorilẹ-ede Naijiria lati yọju si ajọ FBI bi o ba dawọn loju pe, wọn ko lu ẹnikẹni ni jibiti.

Abike Dabiri-Erewa, ti n ṣe alaga ẹgbẹ naa lo sọ eyi ninu ọrọ to fi lede.

FBI List: Ìwa jìbìtì kìí jẹ́ kí àwọn ọmọ Naijiria rí olùrànlọ́wọ́ lókè òkun

Iwa gbájúẹ̀ yii ti n bi Ige ati Adubi -Ojọgbọn Oni Fagbohungbe.

Laipẹ ni ileeṣẹ to n gbogun tiwa ibajẹ ni America gbe orukọ awọn ọmọ Naijiria sita lori iwa jibiti Ọwọ́ òfin ti tẹ ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn jìbìtì l'Amẹrika- FBI

Ọjọgbọn kan ti ni, bi ajọ ọtẹlemuyẹ Amẹrika, FBI, ṣe fi orukọ awọn ọmọ Naijiria lede gẹgẹ bi afurasi oni jibiti, kii ṣe ohun ti o buyi fun wa.

Ọjọgbọn Oni Fagbohungbe, ẹni ti o jẹ adari ẹka imọ bi awọn eniyan ṣe n ronu ni Fasiti ijọba apapọ ti ilu Eko, ni iru iroyin bẹẹ maa n jẹ ki awọn ara ilẹ okeere ri awọn ọmọ Naijria gẹgẹ bi ọdaran ni.

O tẹ siwaju pe: "iru iwa jibiti yi kii jẹ ki awọn ọmọ wa ri oluranlọwọ, ati pe o lee jẹ ki awọn oludokoowo fa sẹyin lorilẹ-ede wa.

Image copyright @FBI
Àkọlé àwòrán Ogọ́rin ọmọ Nàìjíríà ni Iléesẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà FBI, ti forúkọ wọn léde lórí èṣùn jìbìtì

Iwa buburu bayi lee mu ki awọn ọmọ Naijiria koju ọpọlọpọ isoro nigba ti wọn ba n lọ si ilẹ okeere, paapaa julọ nibudokọ ofurufu.

Onwoye naa ro pe awọn obi ni iṣẹ pupọ lati se nipa kikọ awọn ọmọ wọn lọna ti o tọ.

Kii ṣe lati maa fi wọn we awọn ojugba wọn ti o lowo lọwọ, ti wọn ko si mọ ibi ti wọn ti ri owo ti wọn n na.

Bẹẹ, ti a ba fi ọmọ we ọmọ ni owe awọn agab n wi.

Ojọgbọn Oni tẹsiwaju ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC pe: Ijọba ni lati pese iṣẹ fun awọn ọdọ to n fẹsẹ gbalẹ kiri.

Ijọba si tun ni lati fi iya ti o tọ jẹ ẹnikẹni ti ọwọ ofin ba tẹ pe o hu iwa ibajẹ, lai ro iru ẹya ti iru ẹni bẹẹ ti wa ati ẹsin to n sìn.

Bakan naa ni ọjọgbọn Oni Fagbohungbe sọrọ siwaju pe, ijọba ni i ṣe pupọ lati ṣẹ lori igbogunti iwa ibajẹ lorilẹ-ede yi.

O ni ki obi ati alagbatọ fi ibẹru Olorun tọ awọn ọmọ wọn ki wọn si jẹ ki wọn mọ nipa iṣẹ ati ere awọn akikanju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJoe Igbokwe kò yẹ́ fún ipò ti wọ́n fún nípìnlẹ̀ Eko - Babatunde Gbadamosi