Kò sí ẹni tó lè yọ mi nípò Sẹnetọ -Dino Melaye

Image copyright @Dino
Àkọlé àwòrán Irọ lẹ pa lori ọrọ igbẹjọ mi - Dino

Igbẹjọ to n gbọ ẹjọ ẹsun idibo lo ṣẹṣẹ gbe idajọ rẹ sita bayii.

Senetọ Dino Melaye ni ajọ INEC kede pe o wọle idibo ti o waye lọṣu keji ọdun yii nibi to ti dije lati ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Kogi.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni Dino Melaye ba dije to si ti jawe olubori ninu idibo naa to ti tun lọ bẹrẹ iṣẹ nile igbimọ aṣofin agba ni Abuja.

Dino Melaye lo ti kọkọ ṣoju ẹkun yii pẹlu oriṣiriṣi iṣẹlẹ ṣeyin.

Adajọ ile ẹjọ igbẹjọ idibo Naijiria ti ni ki wọn lọ tun ibo naa di ni ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Kogi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAgbẹnusọ Mélayé: Dino ti lọ yọjú sọ́dọ̀ ọlọ́paa SARS

Senetọ Dino Melaye ti ni ki awọn eniyan oun lọ fi ọkan balẹ.

O ni ko sẹni to le yọ oun nipo rara nitori pe awọn to ni ifẹ oun lo dibo yan oun wọle.

Senetọ Dino Melaye ni oun n lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun lati gba idajọ to yẹ.

O ni tootọ ni idibo miran maa waye nipinlẹ Kogi nitori oun yoo di gomina ti Kogi n reti.

Dino Melaye ni ẹru ko ba odo oun rara lori ipo aṣojuṣofin oun ni abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ̀rù ń bá wá lóri ilera sẹnatọ Dino Melaye

Igbẹjọ yii waye ni Lọkoja to jẹ olu ilu ipinlẹ Kogi nibi ti oludije ipo sẹnetọ fun ẹgbẹ APC, Senetọ Smart Adeyẹmi ti pe ẹjọ kotemilorun.

Loṣu kẹrin ni Adeyẹmi Smart pe ẹjọ naa pe oun lo bori ninu idibo fun ipo aṣojuṣofin ẹkun yii.

Oṣu kọkanla ọdun yii ni ajọ eleto idibo INEC ni eto idibo gomina nipinlẹ Kogi yoo waye.

Dino Melaye ni oun lo maa rẹrin igbẹyin lori gbogbo iṣẹlẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDino Melaye nánwó fún Ayefẹlẹ lójú agbo