Ogun Kidnap: Ìjàmbá ṣàwọn ajínigbé tó fẹ́ fipá gba akẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ ọlọ́pàá

Bashir Makama Image copyright Facebook/Ogun Police Command
Àkọlé àwòrán Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ogun

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kepe awọn eeyan ati ile iwosan kaakiri ipinlẹ naa pe ki wọn kan si ile iṣẹ ọlọpaa ti wọn ba ri ẹnikẹni to ba ni apa ibọn lara.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi to ba BBC Yoruba sọrọ, ṣalaye pe awọn akẹgbẹ awọn ajinigbe mẹrin ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ lo doju ija kọ awọn ọlọpaa nigba ti wọn n kọ wọn si Abeokuta lati Ode Omi ti wọn ti ji ọmọ Imaamu ati eeyan meji mii gbe.

DSP Oyeyemi fidi rẹ mu lẹ pe ibọn ọkan lara awọn to doju ika kọ awọn ọlọpaa naa gbẹmi mi tawọn yoku si farapa.

Ọgbẹni Oyeyemi ni iwadii si n lọ lọwọ lori awọn ajinigbe to fara gbọta nitori ko sẹni to tii sọ ohun kan fun ileeṣẹ ọlọpaa di akoko yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ doola awọn mẹta ti wọn jigbe lọsẹ to lọ.

Ẹwẹ, DSP Oyeyemi tun ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpa si n wa ọkọ oju omi agbera pa wọn tawọn ajinigbe gbe lọ nigba ti wọn fi doola ọmọ Imaamu atawọn meji ti wọn gbe lọwọ wọn.

O ṣalaye pe awọn ọlọpaa fẹ kọkọ wa awọn ajinigbe ri ki wọn to wa ọkọ oju omi.