COZA RAPE Allegation: Ìdí rèé tí mi ò fi yọjú sí ìgbìmọ̀ àjọ PFN- Fatoyinbo

BiodunFatoyinbo & BusolaDakolo

Oludasilẹ ijọ Commonwealth Of Zion Assembly ti ọpọ mọ si COZA, Biodun Fatoyinbo ti iyawo gbajugbaja olorin Timi Dakolo, Busola Dakolo fẹsun ifipabanilopọ kan ti ṣaleye pe agbẹjọro oun lo gba oun ni imọran pe k'oun maa yọju si igbimọ ajọ PFN.

Fatoyinbo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lati ọwọ amugbalẹgbẹ rẹ, Ademola Adetuberu.

O sọ ninu atẹjade naa pe o ti gbangba pe igbimọ PFN yoo ṣegbe lẹyin ẹnikan ni ko jẹ ki oun lọ siwaju wọn.

Adetuberu ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe lootọ ni pasitọ Akinola Akinwale pe Fatoyinbo lori aago pe ko wa farahan niwaju igbimọ PFN, ṣugbọn COZA sọ fun un pe ko le wa nitori iwadii si n lọ lọwọ lori ẹsun ti Busola fi kan an.

O fikun ọrọ pe agbẹjọro sọ fun Fatoyinbo wi pe ko maa yọju si igbimọ naa nitori aarẹ ajọ PFN, Bisọpu Felix Omobude ti sọ tẹlẹ pe oun o mọ Fatoyinbo ri.

Adetuberu tun sọ pe niṣe ni igbimọ ajọ PFN tun kọ lati fi iwe pe Fatoyinbo.

O ni Fatoyinbo yoo yọju si igbimọ PFN tawọn ọlọpaa ba pari iṣẹ iwadii wọn lori ọrọ naa.

PFN: Fatoyinbo kọ̀ láti yọjú ni ìwádìí wa kò ṣe parí

Ajo awọn ẹni ẹmi ni Naijiria, eyi ti wọn n pé ni Pentecostal Fellowship of Nigeria (PFN), ti fi ọrọ lede pe awọn ko tii pari iwadii ti wọn n ṣe lori ẹsun ifipabanilopọ ti Busọla Dakolo fi kan Biọdun Fatoyinbo.

Ẹni ti o jẹ akọwe fun ẹgbẹ naa, Biṣọọbu Emma Isong lo fi ọrọ naa lede nigba ti o n ba ileeṣẹ BBC sọrọ nilu Eko lowurọ oni.

O sọ ninu ifọrọweró naa pe: olusọ agutan Biodun Fatoyinbo kọ lati yọju si ibi iwadii ti ajọ naa gbe kalẹ, bi o tilẹ jẹ pe, Busọla Dakolo ti yọju nitirẹ.

Àkọlé àwòrán,

Fatoyinbo kọ̀ láti yọjú ni ìwáàdí ò ṣe parí

Awọn ajọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé ìjọsìn pẹntikọsita ní Nàìjíríà (PFN) ti so pe iwadi ajọ naa si ẹsun ifipabanilopọ ti Busola Dakolo fi kan oludasilẹ ijọ Commonwealth of Zion Assembly (COZA), Pasitọ Biodun Fatoyinbo ko pari.

Àkọlé àwòrán,

Ìwáàdí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kò tíì parí

Ajọ PFN sọ pe iwadii naa ko pari nitori Pasitọ Fatoyinbo kọ lati yọju si igbimọ ẹlẹni marun-un to n ṣewadii ẹsun naa.

O te siwaju ninu ọrọ pe "iwadii ti ẹgbẹ PFN ṣe ko nii ṣe pelu iwadii ti awọn ọlọpaa."

Àkọlé fídíò,

COZA: Ọpọ èrò ló jáde ṣe lòdì sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ Fatoyinbo

Iwadii ẹgbe PFN lo waye nitori awuyewuye awọn eniyan ati awọn oniroyin lori ẹsun naa.

Àkọlé àwòrán,

A gbọ ẹjọ ẹnikan da...