"Ojú wa rí tó ní Egypt, bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ wá lọ́mú, ni wọ́n ń gbá wa ní ìdí"
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yorùbá dùn Egypt: Bàálù méjì yóò kún tí ìjọba bá ṣèrànwọ́ láti kó wa kúrò ní Egypt

BBC Yoruba fẹsẹ kan de orilẹede Egypt lati lọ bẹ awọn ọmọ Oduduwa to wa nibẹ wo, a si ri pe ohun ti wọn n la kọja nibẹ ya ni lẹnu pupọ.

Nigba ti wọn n ba wa sọrọ, awọn ọmọ ẹgbẹ Yoruba dun lasa salaye pe, ko si bo ti wu ki awọn mura daada to, awọn ọkunrin ni Egypt yoo papa tẹ awọn lọyan, gba awọn ni idi, ti wọn yoo si tun da awọn laamu.

Wọn ni suuru gidigidi ni awọn fi n ba awọn ọmọ Egypt gbe, ti ihuwasi ati asa wọn si yatọ gedegede si ti awa ọmọ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, wọn sọ ọpọ aayan ti wọn n se lati ri daju pe awọn ko gbagbe asa ati ise wa, ti wọn si n fi kọ awọn ọmọ wọn ti wọn bi si ajo pẹlu.

Ẹ wo ẹkunrẹrẹ fidio yii, lati mọ ohun ti oju awọn ọmọ Yoruba to wa ni Egypt n ri lọwọ awọn ọmọ onilu.