Lizzy Anjorin: Ẹ má bú mi, ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà ni kìí bá mi yọ̀ fún ire mi

Lizzy Anjorin Image copyright Instagram/lizzyanjorin

Oju opo Instagram tun ti n gbona jain-jain bayii nitori awọn ololufẹ awọn osere tiata obinrin meji, Toyin Abraham ati Lizzy Anjọrin, ti wsn n tahun si ara wọn.

Idi ti isẹlẹ naa se waye ni bi Lizzy Anjọrin se n ba Ronkẹ Odusanya yọ pe o ku ayọ ọmọ tuntun to bi lẹyin ọjọ diẹ ti iroyin gbalẹ pe Toyin Abraham bi ọmọ tuntun.

Ọkan lara awọn ololufẹ Toyin Abraham lo wa ta gba Lizzy pe ki lo de to fi n ba Ronkẹ yọ, to si kọ lati ba Toyin yọ lasiko to bimọ tiẹ.

Ibeere yii lo bi Lizzy ati awọn ololufẹ rẹ ninu, ti wọn si n beere pada pe igba melo gan ni Toyin funra rẹ yọ pẹlu Lizzy lasiko to ba kede loju opo Instagram rẹ pe oun n se nkan ayọ abi oriire.

Ninu alaye rẹ loju opo Instagram rẹ, Lizzy ni "Se bi emi ni mo dide lati ja fun Toyin Abraham lasiko tawọn eeyan n tabuku rẹ loju opo ayelujara nigba ti isẹlẹ ti Seun Ẹgbẹẹgbẹ waye, amọ titi di asiko yii, Toyin ko ki mi ri ku oriiire lasiko ti mo ba kede pe Ọlọrun se oore nla fun mi."

"Mo ti kede lọjọ Kẹjọ osu Kinni ọdun 2019 pe mo n se iranti mama mi, lọjọ kẹtala ni mo joye ẹsin, ọjọ Kẹrinla osu Kẹrin ni mo se ọjọ ibi, ti ọmọ mi si se ọjọ ibi tiẹ ni ọjọ Kẹfa osu Kẹfa, bẹẹ ni mo si ile tuntun lọjọ Kọkanla osu Keje, ams ko si ibi ti Toyin Abraham ti ba mi yọ rara lasiko awọn ayẹyẹ naa."

Image copyright Instagram/lizzyanjorin

Lizzy fi kun pelọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Keje naa ni ẹnikan n dunkoko lati pa oun, ti oun si gbe soju opo Instagram oun, amọ ẹtahoro awọn osere lo sọ le ohun ti mo fi sita yii, ti ọpọ wọn ko si fọhun lati ja fun mi, awọn ololufẹ mi ko si ba wọn ja le lori.

O ni bi oun ba n jo lati Osu Kinini ọdun wọ osu Kejila, o loju osere tiata ti yoo sọ pe oun ri oun, koda, awọn itan aye oun ti oun kọ lasiko ti oun n sile, lee gba omi loju ẹni to ba ti jẹ ori ahun, sugbọn sibẹ, diẹ ninu awọn osere yii lo da si ọrọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin eyi ni Lizzy, ẹni to sẹsẹ ti Mecca de fun isẹ Hajj, wa fi epe silẹ fun awọn to ba n tabuku oun per oun ko ba Toyin Abraham yọ lori ọmọ to bi.

Wayi o, Lizzy wa salaye lẹyin o rẹyin pe oun kuku ki Toyin ku oriire ọmọ tuntun amọ oun ko polowo tabi gbe larugẹ gẹgẹ bi awọn osere yoku tii n se, ni ko jẹ ki ọpọ eeyan mọ pe oun ki Toyin ku ewu ọmọ.

O fikun pe Toyin naa si fesi pada fun oun pe awọn nifẹ, tawọn si ms riri oun pẹlu.

O wa kilọ fun awọn gbọyi-sọyi lati sọra gidi.