Kolawọle Ajeyẹmi: Ó yẹ ká ro ọjọ́ ìkúnlẹ̀ bímọ mọ́ aya lára lásìkò tó bá ṣẹ̀ wá

Kolawole Ajeyemi gbe ọmọ tuntun lọwọ Image copyright Instagram/KolawoleAjeyemi

Obiri ti wọn n pe ni obinrin! Kolawole Ajeyemi, to ṣẹṣẹ bi ọmọ tuntun jojolo pẹlu gbajugbaja oṣere tiata, Toyin Abraham, ti ṣapejuuwe awọn obinrin gẹgẹ bi ohun eelo ẹlẹgẹ lawujọ.

Ṣugbọn o ni bi wọn ṣe jẹ ohun ẹlẹgẹ, naa ni wọn ṣe lagbara to, pẹlu afikun pe ti Eleduwa ba fi obinrin rere jinki ọkunrin kan, iru ọkunrin bẹẹ ti ri ibukun, idunnu ati ẹmi gigun gba lọdọ Ọlọrun.

O ni wiwa pẹlu aya oun, Toyin lasiko to wa nile igbẹbi, to si n rọbi lọwọ, ti jẹ ki oun mọ ohun to maa n jẹ ki awọn ọkunrin kan maa n kẹ iyawo wọn gẹgẹ, toju-timu.

Image copyright Instagram/KolawoleAjeyemi

Ọkọ Toyin, ẹni to sọrọ naa loju opo Instagram rẹ, @kolawoleajeyemi ni ṣe irora, omije ati ọpọ nkan miran ti ko see sọ, ti aya oun la kọja nigba to fẹ bi ọmọ ti Ọlọrun fi tawọn lọrẹ ni k'oun sọ ni, o ni ẹnu oun ko le sọọ tan.

Ajeyẹmi ohun toju awọn obinrin n ri nigba ibimọ ti to kawọn ọkọ wọn maa dariji wọn nigba ti wọn ba ṣẹ wọn.

O wa rọ awọn ọkunrin wi pe ki wọn gbiyanju lati tọju iyawo wọn nitori awọn lo jẹ iya ati iyawo fun wọn.

Amọ ko sai yan pe, arọwa oun fawọn ọkunrin lati maa tẹ jẹjẹ pẹlu awọn aya wọn ko tumọ si pe, oun n fun awọn obinrin lasẹ lati maa siwahu, sugbọn ohun ti oun n sọ ni pe awọn obinrin nilo ikẹ ọkunrin.

Image copyright Instagram/KolawoleAjeyemi

O ni " Ẹ́ jẹ ka maa tọju, ka si maa sikẹ awọn obinrin nitori awọn ni iya ati iyawo wa, ko si ohun meji to tọ si wọn ju ojurere wa lọ, mo si bọwọ fun awọn obinrin rere."

Ajeyẹmi wa gbadura fun gbogbo awọn obinrin rere fun ibukun Ọlọrun lori wọn, bakan naa lo gbadura pe wọn o jere iṣẹ ọwọ wọn.