Drug Trafficking: Ọmọ Yorùbá 16 ló wà nínú 23 tíjọba Saudi fẹ pa

Awọn ọdaran kan ti wọn yẹgi fun Image copyright Getty Images

O kere tan ọmọ Naijiria mẹtalelogun lo wa lara awọn ti wọn fẹ pa lorilẹede Saudi Arabia bayii lori ẹsun pe wọn gbe oogun oloro wọ ilẹ naa.

Atẹjade kan ti ijọba orilẹede Saudi Arabia fi sita lọjọ Abamẹta fihan pe, awọn ọmọ Naijiria yii wa lara awọn ti wọn mu ni papakọ ofurufu King Abdul-Aziz nilu Jeddah ati ti Prince Muhammad Bin Abdu-Aziz ni Madinah, laarin ọdun 2016 si 2017.

Awọn afurasi yii ni wọn sọ pe wọn gbe oogun oloro mii wọ ilẹ naa, eleyi to lodi si ofin orilẹede Saudi Arabia, ati pe iku ni ijiya fun iru ẹsun bẹẹ.

Gẹgẹ bi iroyin naa ti wi ọmọ Yoruba mẹrindinlogun lo wa ninu orukọ eeyan mẹtalelogun ti ijọba Saudi Arabia kede pe awọn yoo yẹgi fun lori ẹsun gbigbe oogun oloro.

Orukọ awọn eeyan ti wọn kede ọhun ree: Adeniyi Adebayo Zikri, Tunde Ibrahim, Jimoh Ishola Lawal, Lolo Babatunde, Sulaiman Tunde, Idris Adewumi Adepoju, Abdul Raimi Awela Ajibola ati Yusuf Makeen Ajiboye.

Awọn yoku ni Adam Idris Abubakar, Saka Zakaria, Biola Lawal, Isa Abubakar Adam, Ibrahim Chiroma, Hafis Amosu, Aliu Muhammad, Funmilayo Omoyemi Bishi, Mistura Yekini, Amina Ajoke Alabi, Kuburat Ibrahim, Alhaja Olufunke Alọlade Abdulqadir, Fawsat Balogun Alabi, Aisha Muhammad Amira ati Adebayo Zakariya.

Image copyright Twitter/Saudi Embassy

Laipẹ yii ni wọn pa ọmọ Naijiria kan ni Saudi Arabia, Kudirat Afolabi lori ẹsun pe o gbe oogun oloro wọ orilẹede ọhun.

Bakan naa, ọmọ Naijiria mii wa lara awọn eeyan kan ti wọn fẹsun kan pe wọn ka egboogi oloro ''cocaine'' mọ lọwọ niluu Jeddah.