Ìdẹ̀ra dé, Gẹnẹrátọ̀ tó ń lo omi dé, a bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Water Generator: Ó leè ṣiṣẹ fún wákàtí mẹfà, kó tó sinmi

Ara meeriri, a ti ri ori ologbo lori atẹ.

Ara ti awọn oyinbo ko lee da, ọmọ Naijiria kan ree to n daa, nipa sise agbekalẹ ẹrọ kan to n pese ina ọba latipasẹ amulo omi lasan.

Nigba to n sọ asiri ẹrọ naa fun ileesẹ BBC, ọkunrin ọhun salaye pe, ọna lati yọ awọn ọmọ Naijiria kuro ninu okunkun, ki wọn si maa ri ina ọba lo ni owo ti ko gunpa lo ti oun lati se ẹrọ amunawa naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O salaye pe ẹrọ naa le sisẹ fun wakati mẹfa, ko to sinmi, ti ko si ni lo ju lita omi kan lọ.

Amọ sa, o ni oun si n dan isọwọ sisẹ ẹrọ naa wo lọwọ, lati mọ kudiẹ-kudiẹ to ku lara rẹ, ki oun to gbe sori atẹ, inu oun yoo si dun lati maa ri ẹrọ ọhun tawọn eeyan ba n lo ninu ile wọn.

Ẹ jẹ ka jọ foju se mẹrin bi ẹrọ naa se n sisẹ si.