APC: O jẹ́ tètè jẹ́wọ́ àwọn tó rán ọ níṣẹ́ torí àwa kìí fún apààyàn lówó

Hamisu Bala pẹlu awọn ọlọpa Image copyright @PoliceNG

Yoruba ni to ba buru tan, iwọ nikan ni yoo ku.

Bẹẹ lọrọ ri fun afurasi ajinigbe kan ti ẹnu ko sin lara rẹ lẹnu ọjọ mẹta yii, Hamisu Bala, ti gbogbo eeyan mọ si Wadume, ẹni to kede pe ẹgbẹ oselu APC fun oun ni miliọnu mẹtala naira lasiko eto idibo apapọ to kọja.

Bẹẹ ba gbagbe, afurasi yii ni awọn ọlọpa fẹ gbe nipinlẹ Taraba, amọ ti awọn ologun gbaa silẹ, ti wọn si gbẹmi ọlọpa mẹta ati araalu kan lasiko isẹlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti ọwọ wa tẹ Wadume, lo ba figbe ta pe oun kii se apaayan abi ajinigbe rara, oloselu ni oun, ti ẹgbẹ oselu APC si mọ oun bii ẹni mọ owo, koda wọn fun oun ni miliọnu mẹtala naira lasiko ibo to kọja fun ipolongo ibo, amọ ti oun na miliọnu meje naira nibẹ.

Image copyright @PoliceNG

Sugbọn niwọn igba to jẹ pe oku ni eeyan pa irọ mọ ti kii lee fọhun, ẹgbẹ oselu APC ti wa kigbe sita fun Wadume pe, yoo dara ko tete sọ awọn to ran nisẹ ibi nitori APC kii fun awọn apaayan ati ajinigbe ni owo.

Lanre Issa Onilu, tii se akọwe ipolongo apapọ fun ẹgbẹ APC salaye pe, ọrọ Wadume dabi afomọ to n wa gbongbo ti yoo so mọ ni lasiko to fẹ subu sinu odo, o si di dandan ki Wadume to n koju idajọ fẹ wa awọn ti yoo fẹyin ti ni.

Image copyright @APC

"Ẹgbẹ tiwa kii ya owo sọtọ fun awọn janduku. Asiko yii yatọ si igba ti ẹgbẹ to n sejọba maa n tọwọ bọ apo ilu lati fi owo gbọ bukata ipolongo ibo ati idibo pẹlu, bi ọwọ eku ẹgbẹ oselu wa se mọ, lo fi n họri lasiko yii."

Onilu ni, taa ba gbọ ohun ti Wadume sọ yii daada, a jẹ pe ọmọ ẹgbẹ APC ni yoo jẹ pẹlu awọn alaye to se.